NBC kò láṣẹ lábẹ́ òfin láti ní kí àwọn iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ máa san owó ìtanràn – Ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, NBC
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ pe ajọ to n ri si igbohunsafẹfẹ ni Naiiria, NBC, ko laṣẹ lati sọ pe ki awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ san owo itanran.
Adajọ James Omotosho ti ile ẹjọ naa lo paṣẹ bẹẹ, o tun wọgile owo itanran ₦500,000 ti NBC paṣẹ ki awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kan san lọjọ kini, oṣu Kẹta, ọdun 2019.
Ninu idajọ rẹ, ile ẹjọ naa pipa irufẹ aṣẹ bẹẹ kọja agbara ti ofin fun NBC.
O sọ siwaju si pe niwọn igba ti NBC kii ṣe ile ẹjọ, ko lagbara lati maa paṣẹ fun awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ pe ki wọn maa san owo itanran.
Nigba to n ṣedajọ naa, ile ẹjọ ọhun sọ pe ofin NBC to ni ki wọn maa paṣẹ owo itanran gẹgẹ bii iya tako ofin orilẹ-ede Naijiria, eyii to fun ile ẹjọ nikan laṣẹ lati pa irufẹ aṣẹ bẹẹ.
O ni ile ẹjọ ọhun ko ni la oju rẹ silẹ ki NBC maa paṣẹ bo ṣe wu u lai bọwọ fun ile ẹjọ.
Adajọ Omotosho sọ siwaju si pe ko NBC tẹle ilana ofin niwọn igba ti oun funra rẹ n ṣe bii olupẹjọ, ile ẹjọ ati adajọ lasiko kan naa.
Adajọ naa tẹsiwaju pe ofin to rọ mọ igbohunsafẹfẹ ni Naijiria, eyii to jẹ ẹka ofin ilẹ yii, ko le fun NBC ni irufẹ aṣẹ kan naa ti ileẹjo le pa, to n tumọ si pe NBC ko laṣẹ lati fi iya jẹ awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ.
O ṣalaye pe niwọn igba ti NBC kii ṣe ileeṣẹ ọlọpaa, ko tọ si i lati maa ṣewadii iwa ọdaran ti yoo yọri si sisan owo itanran.
Ọjọ kini, oṣu Kẹta, ọdun 2019 ni NBC paṣẹ pe ki ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ marundinlaadọta san owo itanra ti iye rẹ jẹ ₦500,000 lori ẹsun pe wọn ṣe lodi si ofin rẹ.
Ẹwẹ, NBC funra rẹ lo pe ẹjọ ti idajọ yii ti jade.












