Igbákejì pásítọ̀ ṣàlàyé bí pásítò Daniel Oluwafeyiropo ṣe fi ipá bá a lòpò lọ́pọ̀ ìgbà

DANIEL OLUWAFEYIROPO

Oríṣun àwòrán, DANIEL OLUWAFEYIROPO

Arabinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan ti ṣalaye bi pasitọ ijọ "I Reign Christian Ministry” ṣe fi ipa ba a lọpọ ni ọpọ igba.

Arabinrin naa to jẹ igbakeji pasitọ ijọ naa tẹlẹ lo ṣalayẹ lẹkunrẹrẹ ni ile ẹjọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye lasiko to jẹ ọmọ ijọ arakunrin naa.

Afẹsunkanni ọhun sọ ni ileẹjọ pe pasitọ naa to jẹ Bisọọbu ni ilu Eko, to si jẹ oludasilẹ ijọ rẹ, Daniel Oluwafeyiropo fi ipa ba oun lọpọ ni igba meji ọtọọtọ pẹlu ileri pe oun fẹ fi ami ororo yan oun.

Oluwafeyiropo ni o n jẹjọ ẹsun ifipabanilọpọ nigun mẹta, to si sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Arabinrin naa sọ fun ileẹjọ pe ipinlẹ Ondo ni oun ti pade pasitọ naa fun igba akọkọ ni ọdun 2018.

O ni ọkan lara awọn ọrẹ rẹ lo fi iwe pe biṣọọbu naa wa si ile ijọsin wọn ti wọn pe akọle rẹ ni ‘’irinajo ẹmi’’ ni osu karun un, ọdun 2018 ni ilu Akungba-Akoko ni ipinlẹ Ondo.

Lẹyin naa lo darapọ mọ ile ijọsin naa to si de ipo igbakeji pasitọ.

Lati ipo igbakeji pasitọ si ẹni ti wọn fi ipa ba lopọ

Ninu ọrọ rẹ, arabinrin naa ni oun ri pasitọ naa gẹgẹ bi baba oun ninu Oluwa, amọ to si fi ipa ba oun lopọ ninu ile rẹ ni agbegbe Lekki, ni osu Kẹfa, ọdun 2020, ni agbegbe Flat 4, Road 2, House 18, Ikota Villa Estate, Lekki.

Bakan naa lo sọ fun ileẹjọ pe biṣọọbu ọhun pe oun ni ori foonu ni Ọjọ karun un, Osu Kẹfa, ọdun 2020 pe ki oun wa si ile oun pẹlu awọn pasitọ miran ni ilu Eko.

Ni Ọjọ Kọkandilogun to de ile biṣọọbu naa lo sọ fun pe o ni ẹjọ lati ro lori ẹsun ti oun fi kan an, ti o si sọ pe yoo tẹ oun ni ọrun.

O ni, ọjọ keji to ku oun ati bisọọbu naa si inu ile ni awọn yooku si ti kuro ninu ile.

Lẹyin naa ni bisọọbu ni ki oun gbadura wakati mẹta kaakiri agbegbe naa, ki oun si pada wa si ile naa.

Arabinrin naa to ni oun pada wale ki wakati mẹta naa to pe ni o bere idi ti oun fi tete de, amọ ti oun ni nitori ojo arọrọda naa ni.

Bi ifipabanilopọ naa ṣe ṣẹlẹ ree

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Obinrin naa ni oun joko si ori aga nibi ti oun ti n gbọ iwaasu Pasitọ Chris, ki biṣọọbu naa to wa si iwaju oun to si sọrọ nipa iwaasu ti oun gbọ naa.

Lẹyin naa lo ni ki oun bọ aṣọ si ihoho, ti ibẹru pe ki pasitọ ma fi ẹsun aini irẹlẹ ọkan oun gẹgẹ bi baba oun ninu Oluwa.

“Amọ mo sọ fun pe mo le ṣe oun gbogbo to fẹ amọ ko ma fi ipa ba mi lopọ, to si tiraka lati fi ẹnu ko mi lẹnu amọ ti mo yẹẹ, to si fọ milẹti.”

“Lẹyin naa lo ni oun kọ mi bi wọn ṣe n bọwọ fun aṣaaju, to si ni angẹli kan wa si ọdọ oun lorun pe mi ko ni tẹriba.

Lẹyinorẹyin, pasitọ naa fi ipa ba a lopọ, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ.

Arabinrin naa ni ọjọ keji lasiko ti oun gbọ iwaasu pasitọ naa ni Bisọọbu naa tun wa joko si ẹgbẹ oun ti o si ni ki oun bọ aṣọ si ihoho.

O ni ibẹru pe iru iṣẹlẹ to waye ni ana tun le waye ni oun si ṣe bi o ṣe fẹ.

“Lẹyin naa lo fi ipa ba mi lọpọ, amọ nitori o tobi jumi lọ, oju ara mi bẹrẹ si ni ṣe ẹjẹ amọ ko dami lohun.”

“Lẹyin to ṣe eleyii tan, lo ni ki n lọ wẹ, to si gba foonu mi, to si nu ẹjẹ naa kuro ki n to wọle pada.”

“Lẹyin naa lo sọ fun mi pe ti mo ba sọ fun ẹnikẹni, mo maa ya were, ti mo si wa ni yara igbalejo titi di ojo keji.

‘’Pasitọ fun mi ni ọpa lati fi bura pe mi o ni sọ fun ẹnikẹni nipa ibalopọ naa’’

Arabinrin naa sọ fun ileẹjọ pe lẹyin iṣẹlẹ naa ni biṣọọbu ọhun fun oun ni ẹgbẹrun marun un naira ki oun fi tọju ara oun titi ti oun yoo fi de lati orilẹede Ghana.

O ni nitori pe oju ara ti o ti fi ipa ba oun lọpọ naa ti da egbo, ti oun si ni eewo ni idi oun ko le tọ mọ.

O tẹsiwaju pe “Mo fi atẹjiṣẹ naa ranṣẹ si pasitọ naa, ti o si ni oun yoo mu mi lọ si ileewosan ni Naijiria ti oun ba pada de lati Ghana.”

“Ni aago mẹta oru lo wa bami ni ile, to si mu ọpa dani pe ki n fi bura ti mo ba maa sọ fun ẹnikẹni nipa ifipabanilopọ naa.”

Pẹlu ibẹru bojo ni mo fi bura naa

“Lẹyin naa lo mu mi lọ si ileewosan First City ni Lẹkki, nibi ti dokita kan, Tina Clement, to jẹ ọkan lara awọn agbagba ni ile ijọsin rẹ ti fun mi ni awọn oogun ati esi ayẹwo.”

“Nigba ti awọn dokita bere oun to ṣẹlẹ si mi, ni mo parọ pe ọkan lara awọn ọrẹ mi lo fi ipa ba mi lọlọ gẹgẹ bi oun ti dokita naa sọ fun mi’’

Lẹyin to sọrọ tan ni ile ẹjọ ni adajọ gba awọn atẹjade atẹjisẹ laarin awọn mejeeji.

Bakan naa ni ẹlomiran fi ẹsun kan pasitọ naa pe o fi ipa mu ọyan oun lẹni ọdun mọkandinlogun.

Labẹ ofin ipinlẹ Eko, ifipabanilopọ tako iwe ofin to de iwa ọdaran ni ipinlẹ Eko, ẹka 260(2) ati 263, ti ọdun 2015.

Adajọ Ramon Oshodi wa sun igbẹjọ naa si Ọjọ Kẹrinlelogun, Oṣu Karun un, ọdun 2023 fun ifọrọwanilẹnuwo.