Ilé ẹjọ́ sún ẹjọ́ tí Peter Obi pè tako èsì ìbò tó gbé Tinubu wọlé síwájú

Oríṣun àwòrán, Tinubu/Obi
Adajọ to n gbọ awuyewuye to waye lasiko eto idibo Aarẹ niluu Abuja, Haruna Tsammani, ti sun igbẹjọ naa siwaju.
Eyii lo waye lẹyin ti adari ikọ awọn agbẹjọro ẹgbẹ oṣelu Labour rọ ile ẹjọ ọhun lati ṣe bẹẹ.
O ni eyii yoo fun awọn lanfani lati yẹ awọn ẹri to wa lọwọ awọn wo finifini, yoo si tun fun awọn lanfani lati yọ awọn ẹri ti ko lẹsẹ nilẹ ninu ẹjọ ti wọn pe.
Lẹyin ti ikọ agbẹjọro LP ati APC fẹnuko tan, ni adajọ naa sun igbẹjọ ọhun si ọsẹ to n bọ, iyẹn Ọjọru, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2023.
Lára àwọn àgbẹjọ́rò ti yóò máa sójú fún ẹgbẹ́ oṣelu Labour Party ni: Ikechukwu Ezechukwu (SAN), Emeka Okonkwo(SAN), Alex Eze, Audi Anka(SAN), Chris Garuba, Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul Ananaba, Ọ̀jọ̀gbọ́n Agbo J.Madaki, ati Chike A.Obi.
Nigba ti Wọlé Olanipekun, Akin Olujim, Yusuf Al, Dr Hassa, O.D.Onoja ati A.A.Malik, ṣoju fun APC.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APP ní àwọn kò ṣẹjọ́ mọ́, Labour Party duró digbí lórí ìgbẹ́jọ́ náà lónìí

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Igbẹjọ tun ti bẹrẹ ni ile ẹjọ gẹgẹ bi igbimọ to n gbọ ẹjọ nipa awọn awuyewuye to ba suyọ lẹyin idibo yoo ṣe gbọ ẹsun ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije rẹ, Peter Obi lodi si aarẹ ti wọn dibo yan, Bola Tinubu.
Wámuwámu ni àwọn agbófinró àti àwọn ọlọ́pàá dúró sẹnú ọ̀nà tó lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Abuja.
Bó ṣe yẹ kí ìgbẹ́jọ́ náà ṣe kọ́kọ́ wáyé ni láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú APP ati Bola Ahmed Tinubu.
Àmọ́, ẹgbẹ́ òṣèlú APP ti ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APP náà ti ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́ ọ́n, nítorí náà wọ́n ní kí ilé- ẹjọ́ fa ìwé ẹ̀sùn náà ya.
Agbẹjọ́rò fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ fún adájọ́ pé àwọn ṣì ń retí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú míràn tí wọ́n yóò sọ pé àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.


Agbẹjọ́rò fún àjọ elétò ìdìbò INEC ti ní àwọn kò takò ẹgbẹ́ òṣèlú kankan ti wọ́n bá ní àwọn kò ṣe ẹjọ́ mọ́.
Ní ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, wọn kò yọjú sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lónìí Ọjọ́rú torí pé wọ́n ti sún ìgbẹ́jọ́ tiwọn síwájú di Ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀.
Láàrọ̀, ilé ẹjọ́ ni àwọn sún ìgbèjọ́ ti Labour Party síwájú sí aago méjì.
Ìwọ́de bẹ́ sílẹ̀ nípa ètò ìgbèjọ́ tó ń lọ lọ́wọ́

Bí àwọn agbófinró ṣe ń dúró láti mójútó ètò ààbò, bẹ́ẹ̀ náà ni orin oríṣi ń wáyé láti ẹnu àwọn tó ń se ìwọ́de.
Ohun tí àwọn olùwọ́de ń sọ ni pé, ki won jẹ́ kí ilé ẹjọ́ se ojúṣe wọn. Kí wọn má ṣe dùn ìkokò mọ́ àwọn ènìyàn.
Olùdarí ikọ̀ ọ̀hún, The Natives, Hon Smart Edward ni àwọn kò fẹ́ ki orílẹ̀-èdè Nàìjíríà dà bìí Sudan, ìdí niyi tí àwọn fi ń se ìwọ́de.

















