Wo àwọn tí ẹnu ń kùn pé ó ṣeéṣe kí wọ́n di Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà

Oríṣun àwòrán, Others
Láìsí ẹ̀gìrì, awọ kò lè wu, ohun tó ń jẹ́ ìjọba àwaarawa kò lè pé láìsí ẹ̀ka ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Bí Ààrẹ tuntun tí Nàìjíríà ń dìbò yàn bá ṣe ń gba ọ̀pá àṣẹ ní ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún ọdún 2023 náà ni agbára yóò máa pàrọ̀ ọwọ́ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn rẹ̀.
Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kefa, ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn tí wọ́n bá búra wọlé tán fún Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tuntun Nàìjíríà ni ìrètí wà pé àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yóò bẹ̀rẹ̀ ìjókòó ti wọn náà pẹ̀lú yíyan àwọn adarí ilé.
Ó kéré tán àwọn sẹ́nétọ̀ mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló ti fi èròńgbà wọn láti di Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin fún sáà ti ilé aṣòfin ìkẹwàá.
BBC News Yorùbá ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn tó ti fi èròńgbà wọn yìí hàn:
Godswill Akpabio

Oríṣun àwòrán, Others
Láàárín ọdún 2007 sí 2015 ni Akpabio fi ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom fún ọdún mẹ́jọ kí Ààrẹ Muhammadu Buhari tó yàn án gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ẹkùn Niger Delta Affairs láàárín ọdún 2019 sí 2022.
Ní ọjọ́ Ajé ni ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC pawọ́pọ̀ fẹnukò pé kí Akpabio jẹ Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.
Ìfẹnukò yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ẹnu ti ń kun ẹgbẹ́ òṣèlú APC pé ẹkùn ààrin gbùngbùn gúúsù orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n sún ipò ọ̀hún sí.
Àmọ́ àwọn ènìyàn kan pàápàá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn ti ń fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí Ìfẹnukò yìí wí pé kò yẹ kí àwọn ará ìta máa dá sí ìyànsípò àwọn adarí ilé aṣòfin.
Bákan náà ni APC tún ní àwọn yan Barau Jibrin láti ìpínlẹ̀ Kano gẹ́gẹ́ bí igbákejì Akpabio.
Orji Uzor Kalu

Oríṣun àwòrán, Others
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹjọ oṣù Karùn-ún ni Kalu kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC pé ó wu òun láti di Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Nàìjíríà fún sáà tuntun tó ń bọ̀ yìí.
Kalu ní òun ní gbogbo àmúyẹ láti fi sin àwọn ọmọ Nàìjíríà tọkàntọkàn tí òun bá rí ipò náà.
Lẹ́tà rẹ̀ ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn aláṣẹ APC ti jáde sí gbangba pé Akpabio ni àwọn fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà.
Ní ọdún 1960 ni wọ́n bí Kalu tó sì ti ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Abia láàárín ọdún 1999 sí 2007.
Òun ni ọlọ́pàá ilé aṣòfin tí yóò wá sí òpin lẹ́yìn tí wọ́n dìbò yan-án gẹ́gẹ́ bí sẹ́nétọ̀ ní ọdún 2019.
Ali Ndume

Oríṣun àwòrán, Others
Láti ọdún 2003 ni Ndume ti ń ṣojú àwọn ènìyàn Borno ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Láàárín ọdún 2003 sí 2011 ló fi jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin kí wọ́n tó yàn-án sí ipò sẹ́nétọ̀ lọ́dún 2011.
Ní ọdún 1959 ni wọ́n bí Ndume tó sì ti fi ìgbà kan rí jẹ́ olórí ọmọ ilé aṣòfin tó kéré jùlọ.
Ndume ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò yan Akpabio lé àwọn ọmọ ilé lórí àti pé àbá lásán ni APC dá.
Ẹkùn ìlà oòrùn Nàìjíríà tí igbákejì Ààrẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn, Kassim Shetima ti wá náà ni Ndume ti wá.
Osita Izunaso

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹkùn ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Imo (Orlu) ni Izunaso yóò máa soju ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Ó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé aṣòfin láàárín ọdún 2007 sí 2011 kó tó di wí pé wọ́n tún dìbò yàn án lọ́dún 2023.
Ọdún 1966 ni wọ́n bí Izunaso tó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ní ọdún 1992 ni wọ́n kọ́kọ́ dìbò yàn án sí ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, kí wọ́n tó tún dìbò fún un sípò yìí kan náà lọ́dún 1999.
Àwọn tó ń léwájú nínú àwọn tó ń wá ipò Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà nìyí, ojú rèé ìran rèé títí di ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfà tí ètò ìdìbò wọn yóò máa wáyé.












