Eze Ndigbo tó ní òun yóò fìwé pe IPOB wá sí Eko fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìgbésùmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, @DeeOneAyekooto
Ijọba ipinlẹ eko ti gbe Eze Ndigbo ti agbegbe Ajao Estate, Frederick Nwajago, lọ sile ẹjọ lori ẹsun igbesumọmi.
Ẹsun mẹsan-an ọtọtọ ni wọn fi kan afurasi naa nile ẹjọ giga to wa ni gbagede Tafawa Balewa Square, l’Eko.
Lara ẹsun naa ni pe o n “hu iwa igbesumọmi, o kopa ninu igbesumọmi, o n ṣe ipade pẹlu ẹgbẹ ti ijọba ti fofin de, o gbiyanju lati ṣe iranlọwọ owo fun igbesumọmi ati pe o n mura lati wu iwa igbesumọmi” niluu Eko.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fi ṣikun ofin mu ọkunrin naa lọjọ kini, oṣu Kẹrin, ọdun yii lẹyin to ṣe fidio kan, nibi to ti sọ pe oun yoo fi iwe pe ẹgbẹ ajijagbara, IPOB, lati wa maa ṣọ ṣọọbu awọn ẹya Igbo niluu Eko.
Ninu fidio naa, Nwajago ni “IPOB, a o fiwe pe wọn, ko si iṣẹ ti wọn n ṣe.”
“Gbogbo awọn IPOB yoo wa maa daabo bo awọn ṣọọbu wa, a o si san owo fun wọn... a ni lati bojuto ara wa ki wọn le dẹkun ati maa ṣakọlu si wa laarin oru, laarọ ati lọsan.”
“Mi o sọrọ mi ni ikọkọ, ẹ jẹ ki gbogbo aye gbọ ohun ti mo n sọ, awọn ẹya Igbo gbọdọ gba ẹtọ wọn nipinlẹ Eko.”
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin sọ pe awọn ko ni faye gba IPOB lati ribi joko nipinlẹ naa.
Nigba ti wọn kọkọ mu afurasin ọhun, ile ẹjọ majistreeti to wa ni Yaba ni wọn kọkọ gbe lọ, nibi ti adajọ ti paṣẹ pe ki wọn gbe lọ sọgba ẹwọn nigba ti igbẹjọ rẹ yoo maa lọ.
Nigba ti wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan an niwaju rẹ nile ẹjọ, afurasi naa ni oun ko jẹbi ọkankan ninu gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun kan,
Ile ẹjọ ọhun ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2023.












