Àwọn aṣòfin tuntun dá ẹgbẹ míràn sílẹ̀ nínú Ilé Ìgbímọ̀ Aṣòfin Naijiria láti yan ẹ̀ni tí wọ́n fẹ́ gẹ́gẹ́ bíi adarí

Awọn aṣofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lọ si ile igbimọ aṣofin ni Naijiria ti parapọ lati da ẹgbẹ tuntun silẹ ni Ile Igbimọ aṣofin.
Eyi n waye lasiko ti wọn n gbaradi lati yan adari ile igbimọ aṣofin tuntun, eleyii ti yoo fidimulẹ ni ipari oṣu karun un, ọdun 2023.
Awọn ẹgbẹ naa lo pe ara wọn ni 'New Vision 10th Assembly', ti awọn to si wa ninu ẹgbẹ naa si le ni igba eniyan bayii.
Awọn adari ẹgbẹ tuntun naa ni wọn da ẹgbẹ naa silẹ lati jẹ ki awọn aṣofin tuntun naa ni ẹnu ọrọ ni Ile Igbimọ aṣofin.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ tuntun ọhun, Bashir Usman Gorau, ni awọn aṣofin to ti wa ni Ile Igbimọ aṣofin tẹlẹ n dẹyẹ si wọn, pe idi ree ti awọn fi da ẹgbẹ naa silẹ.
Awọn ẹgbẹ oṣelu to wa ninu ẹgbẹ naa wa lati ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), New Nigeria Peoples Party (NNPP), Peoples Democratic Party (PDP), Labour Party (LP), ati awọn ẹgbẹ oṣelu miran.
"Aṣofin Betara ni a ṣagbatẹru fun lati di ipo abẹnugan Ile Igbimọ aṣofin mu’’

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa ni aṣofin Muktar Betara ni awọn fẹ ko di ipo abẹnugan Ile Igbimọ aṣofin mu ni Naijiria.
Betara ni aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Biu/Bayo/Shani ni ipinlẹ Borno.
Awọn aṣofin naa ni awọn fi ipinu wọn han lasiko ti wọn gba awọn aṣofin lati iha Guusu-Guusu Naijiria wọle si inu ẹgbẹ wọn.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa ni awọn gbagbọ pe Betara lo pegede julọ ninu gbogbo awọn to n didje du ipo naa.
Bakan naa lo ni awọn ti n kaakiri awọn agbegbe ni Naijiria lati sọ rere nipa ẹni ti wọn fẹ ko di ipo naa mu.























