Ọlọrun ló pè mí láti dá ìjọ tí Musulumi àti Kristẹni ti ń jọ́sìn papọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà sílẹ̀ – Stainless Elijah
Ọpọ eeyan lo gbagbọ pe Ọlọrun kan naa lawọn ọmọlẹyin Kristi ati Musulumi n sin, bo tilẹ jẹ bi wọn ṣe n jọsin ko jọra wọn, bẹẹ si ni wọn kii ṣaba maa n jọsin lọjọ kan naa.
Amọ ninu irinkerindo BBC Yoruba, a ṣawari ijọ kan niluu Ibadan, nibi ti awọn Musulmi ati Kristẹni ti n jọsin ninu ijọ kan naa, ati lasiko kan naa lai si wahala kankan laarin wọn.
Oludasilẹ ijọ ọhun, Stainless Olwatikayomide Elijah, to jẹ ọmọ bibi ilu Ibadan, sọ pe Ọlọrun lo pe oun lati da ijọ naa silẹ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, inu igbo kan ti wọn n pe ni igbo Àgàlà ni Oluwa dari oun si lati bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ.
Itan fi ye wa pe ẹnikẹni to ba wọ inu igbo yii kii pada jade mọ.
Oludasilẹ naa ni inu igbo ọhun ni oun wa ti oun ti n sin Ọlọrun gẹgẹ bii ẹmi mimọ ṣe dari Jesu sinu iju lẹyin iribọmi rẹ ninu Bibeli.
O ṣalaye pe “Ijọ Ọlọrun ti ọwọ mi gbe kalẹ ni a pe ni World Stainless Church, ṣugbọn nigba to ya, Ọlọrun tun ni gbogbo agbaye loun ran mi si.”
“Mi o ki n ka Bibeli tabi Quran”
O sọ siwaju si pe oun kii ka Bibeli tabi Quaran, ayafi ohun ti Ọlọrun ba sọ fun oun nikan loun maa n ṣe.
“Mi o ki n ka Bibeli kankan, mi o ki n ka Quran kankan, mo kan n ṣe ohun ti Ọlọrun ba ti wi ni.”
Stainless ni iṣẹ ti Ọlọrun ran oun ni lati maa tu awọn eeyan silẹ ninu ogun ti wọn ba n dojukọ, kii ṣe lati fa eeyan kuro ninu ẹsin rẹ si ẹsin miran.

Ki ni awọn ọmọ ijọ sọ?
Lara awọn ọmọ ijọ World Stainless Church to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe awọn ni imọ ẹsin Kristẹni ati ti Musulumi, koda ọkan lara wọn, Lukman Olawale Fasasi, sọ pe oun tilẹ lọ sile ẹkọ bibeli WOFBI, to jẹ ti ijọba Living Faith Church Woldwide.
Fasasi sọ pe awọn kii san owo igba tabi owo ọrẹ kankan ninu ijọ naa, o ni oludasilẹ awọn lo tun maa n fi owo ran awọn ọmọ ijọ lọwọ.
Oludasilẹ ọhun wa pari ọrọ rẹ pe iṣẹ Ọlọrun ni ijọ naa, bi bẹẹ kọ, ko ni rọrun fun awọn Musulumi ati kristẹni maa jọsin papọ nibi kan naa ati lọjọ kan naa lai si wahala kankan.













