Orí kó èrò 143 tó wọ bàálù Max Air yọ l’Abuja lẹ́yìn tí táyà rẹ̀ méjì gbiná yọ lójijì

Papakọ Ofurufu Abuja

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn ero mẹtalelogoje kan ti n kọrin ọpẹ lẹyin ti baalu Max Air ti wọn wọn ko ijamba taya bibẹ lasiko to fẹ balẹ ni Abuja.

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa fi atẹjade sita loju opo wọn ni Twitter eleyi to ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye to si tun fẹsẹ rẹ rinlẹ.

Ninu awọn ero yi la gbọ ke ọmọ kekere kan wa ninu wọn.

Papakọ ofurufu Abuja

Gẹgẹ bi atẹjade yi ṣe wi,Yola ni Adamawa ni baalu naa ti gbera ni nkan bi ago mejia kọja iṣẹ́ju maarun un lọsan to si yẹ ko balẹ ni Abuja ni nkan bi ago mẹta abọ lọjọ Aiku kanna.

Wọn ni bi o ṣe fẹ balẹ ni Abuja lawọn taya rẹ meji kan gbina ṣugbọn lalaafia lawọn ero ati oṣiṣẹ baalu naa wa.

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu ọhun sọ pe gbogbo igbesẹ to yẹ lawọn gbe lati ri pe awọn ero naa ko mọ inira ati pe awọn ṣe itọju wọn lasiko iṣẹlẹ yi.

"A ti paarọ awọn taya baalu naa to si ti lọ si aaye taa ti ṣatunṣe rẹ ki a to lo lati gbe ero lọjọ iwaju''

Wọn lawọn dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ papakọ ofurufu awọn oṣiṣẹ pajawiri ati awọn miran ti wọn pawọpọ lati ri pe ewu kankan ko ba awọn ero ati oṣiṣẹ to wa ninu baalu naa.

Aworan ọkọ baalu ati taya to jona

Oríṣun àwòrán, Max Air/ Twitter

FAAN naa tara ṣe iṣẹ wọ́n bo ṣe yẹ

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ to wa lara awọn ero baalu naa Alhassan Umar sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ FAAN tara ṣe iṣẹ wọn lọna to bojumu.

Ninu fọnran fidio to fi sita ni Facebook, o salaye pe niṣe ni wọn n ba awọn ero baalu sọrọ ti wọn si ri wi pe nkankan ko ṣe ẹru wọn.

O tun fi kun pe awakọ baalu naa dantọ ati pe awọn oṣiṣẹ panapana ati oṣiṣẹ pajawiri mii ni wọn wa ni ṣẹpẹ.

''Bi ṣe yẹ ki nkan ri ree lawọn papakọ ofurufu kaakiri Naijiria kii ṣe lawọn kọọkan ninu wọn.A dupẹ lọdọ Ọlọrun to ṣọ ẹmi wa''

Wo aworan bi awọn arinrinajo ṣe ha si papakọ ofuruku lati oru di aarọ

Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu
Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu
Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu
Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu
Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu
Bi awọn ero Baalu ṣe ha si papakọ ofurufu