₦‎22.4b ni a yà sọ́tọ̀ láti fi bọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n nínú ọdún yìí – Ìjọba àpapọ̀

Prison

Oríṣun àwòrán, Premium Times

Ijọba Naijiria ti kede pe owo ti iye rẹ to ₦‎22.4b ni oun yoo na lati fi bọ awọn ẹlẹwọn lọdun yii.

Akọwe agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle, Shuaib Belgore, lo fi ọrọ naa lede nibi ipade ọlọjọ meji kan lori ọrọ ṣiṣe adinku si iye eeyan to wa lọgba ẹwọn, eyii to waye niluu Abuja.

O ni owo naa ni ijọba la kalẹ lati bọ awọn ẹlẹwọn ninu eto iṣuna ọdun yii.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo igba ni iye awọn ẹlẹwọn n pọ sii ni Naijiria, nnkan bii ida ọgọrin awọn ẹlẹwọn naa ṣi ni ọrọ wọn ṣi wa nile ẹjọ.

Belgore ṣalaye pe ọgba ẹwọn òjìlénígba lé merin (244) lo wa kaakiri Naijiria ti awọn ẹlẹwọn 75,507 si wa ninu wọn.

Eyii to n tumọ si pe ọgba ẹwọn méjílélọ́gọ́rin lo kun akunfaya kaakiri Naijiria.

O ṣalaye siwaju si pe 73,821 ni iye ẹlẹwọn to jẹ ọkunrin, nigba ti awọn obinrin 1,686 wa lọgba kaakiri Naijiria.

Ninu ẹlẹwọn 75,507 ni Naijiria, 52,821 ninu wọn ni ọrọ wọn ṣi wa nile ẹjọ.

23,071 ninu awọn ẹlẹwọn naa ni wọn ti ṣedajọ wọn nigba ti 3,322 lo ti gba idajọ iku.