Wo ìdí tí Ọba tuntun kò ṣe tíì jẹ ní Ogbomọṣọ, Iṣẹyin àti àwọn ìlú méjì míì nípìnlẹ̀ Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Ni kete ti Ọba Alade kan ba ti waja ni eto ati igbese ti maa n bẹrẹ lati yan Ọba tuntun nilẹ Yoruba.
Apẹrẹ ọkan lara awọn ilu ti eto ati yan Ọba tuntun ti fi ẹsẹ mulẹ julọ nilẹ Yoruba ni ilu Ibadan, nitori gbogbo ilu lo ti mọ ẹni ti ipo Ọba kan ki ẹni ti o wa lori Oye to wọ kaa ilẹ sun.
Ilu Ibadan si jẹ ọkan lara awọn ilu ti Ọba ti waja ninu saa akọkọ iṣejọba Gomina Ṣeyi Makinde.
Lara awọn ilu mii ti o tun padanu Ọba wọn ni ilu Igangan, Ogbomọṣọ, Ọyọ ati Iṣẹyin.
Lọjọ keji oṣu kini ọdun 2022 ni Olubadan ana, Oba Saliu Adetunji, re iwal aṣa lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.
Nigba ti yoo fi ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun kan naa, Oloye Agba ati Ọmọwe Mashod Olalekan Balogun gba ewe oye gẹgẹ bii Olubadan ikejilelọgọrin nilẹ Ibadan.
Ọba tuntun jẹ nilẹ Ibadan laarin oṣu mẹta ti Olubadan ana waja nitori eto ati ilana ifinijoye ti wọn lo n'Ibadan.
Titi di asiko yii, awọn ilu mẹrin kan ṣi wa lai ni Ọba tuntun n'ipinlẹ Ọyọ, lẹyin ti awọn Ọba wọn tẹlẹri ti re ibi agba n re.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Akọkọ ninu awọn ilu naa ni ilu Ọyọ Alaafin
Alaafin ana, Kabiyesi Ọba Lamidi Adeyẹmi III re iwalẹ aṣa ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun 2022 lẹni ọdun mẹta lelọgọrin. O le ni aadọta ọdun ti Ọba Adeyemi fi wa lori oye ki ọlọjọ to de.
Lẹyin ipapoda Ọba naa ọkanojọkan awọn idile to n jẹ Ọba nilu Ọyọ bẹrẹ sini sa gbogbo ipa lati rii daju wi pe idile wọn ni Ade Ọba kan.
Ọpọlọpọ awuyewuye lo si ti rọ mọ ipo Ọba naa, nitori bi idile kan ṣe n kede fun awọn oniroyin wi pe awọn kan, ni idile mii tun n fi ọrọ lede wi pe awọn ni.
Ṣugbọn ni nnkan bii ọsẹ diẹ sẹyin ni Ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe oun yo yan Alaafin Oyo tuntun laipẹ, ki awọn eeyan ilu naa lọ ṣe suru.
Makinde, ti oloye Bayo Lawal, to jẹ kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ṣoju fun sọ pe, ijọba ipinlẹ Oyo mọ pe awọn eeyan ilu ọhun ti n reti lati ni Alaafin tuntun.
O ni "Awọn eeyan ti n reti lati ni Ọba tuntun amọ a ni lati tẹle awọn ilana to yẹ."
"A ṣeleri lati maṣe ṣe magomago kankan pẹlu yiyan Alaafin tuntun, amọ ko ni pẹ, ko si ni jina."
Botilẹ jẹ wi pe lẹyin ọrọ ti ijọba sọ ni idile mẹsan an mii to n jẹ Ọba niluu Ọyọ tun ke gbajare wi pe ijọba ipinlẹ Ọyọ fẹ da oju ifinijoye naa ru.
Titi di asiko yii, Ilu Ọyọ ṣi wa lai ni Ọba ati Imaamu agba, nitori ninu oṣu kini ọdun 2023 ni Imaamu agba ilu Ọyọ, Sheikh Mashood Abdul Ganiyy Adebayo, Ajokidero III jade laye.
Alaafin Ọyọ nikan lo si lẹtọ lati yan Imaamu Agba tuntun. O tumọ si wi pe o di igba ti Alaafin tuntun ba jẹ, ki ilu Ọyọ to ki Imaamu agba tuntun kaabọ.

Oríṣun àwòrán, Other
Ilu keji ti ko tii yan Ọba tuntun lẹyin ti Ọba ana papoda ni ilu Ogbomọṣọ.
Lọjọ kejila ọṣu kejila ọdun 2021 ni Ṣọun ana nilu Ogbomọṣọ, Oba Oladunni Oyewumi, Ajagungbade III re iwalẹ aṣa lẹyin ọdun mejidinlaadọta lori oye.
Botilẹ jẹ wi pe eto ati ilana wa lorii jijẹ oye Ṣoun, ọrọ ko tii waye nipa jijẹ Ṣoun tuntun nilu Ogbomọṣọ.
Ọkanojọkan awọn ọmọ Ọba naa ni iroyin ti tọka wọn wi pe awọn ni Ọba kan, ṣugbọn titi di asiko yii, iroyin ko tii jade nipa ẹni ti awọn lọbalọba fa kalẹ, tabi ẹni ti ijọba ibuwọlu.

Oríṣun àwòrán, Other
Ilu ikẹta to wa lai ni Ọba titi di asiko yii, lẹyin ti Ọba wọn pa ipo da ni ilu Iṣẹyin.
Lọjọ kẹrinlelogun ni Aṣẹyin ti ilu Iṣẹyin ana, Ọba Abdul-Ganiyu Salawudeen re iwalẹ aṣa lẹni ọdun mejilelọgọta, lẹyin aisan ranpẹ.
Lẹyin ipapoda Aṣẹyin ni Oluwo Aṣẹyin ti ilu Iṣẹyin, Oloye Ifasoji Adeyemi fi ọrọ lede wi pe owo tabi agbara oṣelu kọ ni yoo yan Aṣẹyin tuntun bikoṣe Ifa.
Ninu ọrọ ti o sọ saaju ọdun Oro lọdun 2022, Adeyẹmi ni ọkan lara awọn idile mẹta ti Ọba kan ti fa eeyan kalẹ, botilẹ jẹ wi pe a ko tun gbọ nnkan kan mọ titi di asiko yii.
L'Ọjọbọ ni iroyin tun gbode wi pe igbesẹ lati ya Asẹyin tuntun ti koju idiwọ ranpẹ, nitori pe Atọkun Oro, Aaba Odofin ti ilu Iṣẹyin, Ashiru Oroleye ti o jẹ alẹnulọrọ ninu igbesẹ lati yan Ọba tuntun jade laye lẹyin aisan ranpẹ.

Oríṣun àwòrán, Other
Ilu kẹrin ti wọn ti n reti ki Ọba tuntun jẹ n'ipinlẹ Ọyọ ni ilu Igangan.
Asigangan ti ilẹ Igangan n'ipinlẹ Ọyọ, Ọba Abdul-Azeez Adewuyi, Aribiyan II waja lọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila ọdun 2021.
Titi di asiko yii, Ọba tuntun ko tii jẹ ni ilu naa.
Gbogbo awọn Ọba to re iwalẹ aṣa lasiko iṣẹjọba Makinde ni saa akọkọ ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe agbatẹru inawo ayẹyẹ ikẹyin ti wọn ṣe fun wọn.
Pẹlu alaye ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe wi pe eto nlọ lọwọ, ireti wa wi pe awọn Ọba tuntun yoo jẹ ni awọn ilu yii laipẹ.












