Mi ò tó láti wọ Bàtà tí Aláàfin bọ́ sílẹ̀́- Arẹmọ Alaafin

Àkọlé fídíò, Ifọrọwerọ pẹlu Arẹmọ Alaafin Oyo to waja
Mi ò tó láti wọ Bàtà tí Aláàfin bọ́ sílẹ̀́- Arẹmọ Alaafin

''Gẹgẹ bi olori ẹbi, bata ti bata wa bọ ọ, emi gaan o le bọ. Mo ṣẹṣẹ n mọ iru ẹru ti baba wa n gbe ni.''

Gbolohun yi lati ẹnu Arẹmọ Oba Israel Babatunde Adeyemi to jẹ akọbi ọkunrin Alaafin Oyo to waja jẹ atọna iru ipa ti Alaafin ko nipa to wa laye.

Ifọrọwerọ yi waye lẹyin ọdun kan ti Alaafin wọ kaa ilẹ lọ.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Arẹmọ tu kẹkẹ ọrọ nipa ọjọ to kẹyin igba ti Alaafin Lamidi Adeyemi dagbere fun duniya e o di gbere.

O sọ pe awọn ti kọkọ fẹ gbe baba lọ si ilẹ okere ṣugbọn lẹyin agbeyẹwo, wọn pinu lati tọju baba ni ile iwosan nla fasiti Afe Babalola.

O ṣalaye pe Alaafin ti n ṣe daada nigba ti oun yoo fi yọju si wọn koda o ni Alaafin ti n ka iwe iroyin gẹgẹ bi iṣe wọn.

Lẹyin igba ti Arẹmọ ni oun fi baba silẹ pada sile ni o ni Alagba Afe Babalola pe lori ago pe Alaafin ti rebi agba ree.

Nipa ṣise lede lẹyin Alaafin, Arẹmọ to jẹ agbẹjọro sọ pe ẹru nla ni baba gbe kalẹ ti awọn si n gbiyanju lati maa gbe diẹdiẹ.

O ṣe alaye pe oun ṣẹṣẹ n mọ riri iru ipa ti Alaafin ko nipa iṣeto ati idari mọlẹbi ati gbogbo awọn ti o wa labẹ akoso wọn.

Nipa oori Alaafin ati eto to n lọ nipa eto rẹ o ni awọn to jẹ agba ti n dahun si.

''Nkan to so mọ Alaafin, awa ọmọ kekere ko le da si.Nipa ti oori, o kọja agbara mi''

O tẹsiwaju pe ibanujẹ ati irẹwẹsi kọkọ de ba mọlẹbi ṣugbọn oun n gbiyanju bayi lati ri pe awọn ọmọ ṣe ara wọn lọkan lẹyin iku Alaafin.

Ọjọ keji le logun oṣu Kẹrin ọdun 2022 ni Alaafin Lamidi waja.

Ẹni ọdun mẹtalelọgọrin ni baba ṣe nigba ti wọn fi papo da.

Lẹyin ọdun kan ti Alaafin waja, wọn ko ti ribi yanju ẹni ti yoo gba ipo naa lẹyin Ọba Lamidi.

Nigba aye Alaafin, o jẹ Ọba to gbe iṣe ati aṣa ilẹ Yoruba larugẹ.

Labẹ isakoso rẹ,ogo ati ẹyẹ de ba ipo Alaafin ti o si jẹ ilumọọka ti ọpọ awọn eekan ilu a maa tọ lọ fun itọsọna ati imọran.