Àìmọye ọkùnrin tó ní àwọn ò lè fẹ́ mi torí iṣẹ́ tí mò ń ṣe – Obìnrin tó ń ṣe POP
Obinrin to n fi iṣẹ POP jẹun, Fatimah Oshorenoyah Musa, ti ṣalaye bo ṣe bẹrẹ iṣẹ naa ati bi irinajo rẹ ṣe ri.
Fatimah, to jẹ ọmọ ipinlẹ Edo amọ ti wọn bi silẹ Yoruba ṣalaye pe iṣẹ nọọsi lo kọkọ wu oun nibẹrẹ pẹpẹ amọ awọn idojukọ kan lo mu oun ya bara sidi iṣe POP.
Lẹyin ti iṣẹ nọọsi ko bọ si, o lọ sile ẹkọ ijọba apapọ, National Open University, NOUN, nibi to ti kẹkọọ nipa imọ ikansiranẹni nilana igbalode.

O ni “Lati ilẹ na, iṣẹ ọkunrin ni mo maa n ṣe nitori ẹgbọn ọkunrin mẹta ni mo ni... nnkan ọkunrin mọ mi lara gan.”
Lẹyinorẹyin, Fatimah ya sidi iṣẹ POP eyii to sọ di eeyan lawujọ lonii.
“Awọn obinrin kii gbe iṣẹ fun mi, ayafi ọkunrin nikan”

Nipa awọn ipenija to wa lẹnu iṣẹ naa, Fatimah sọ pe “Ti mo ba de ibi ti mo ti fẹ gba iṣẹ, wọn a ni ah, obirin! Awọn o le gbe iṣẹ fun obinrin o!”
“Ẹlomii a ni awọn o le gbe’ṣẹ fobibinrin o, to ba ba iṣẹ awọn jẹ nkọ?”
O sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ awọn mii kii fẹ gbe iṣe fun nitori pe oun jẹ obinrin awọn mii yan lati mọọmọ gbe iṣe fun oun nitori pe oun jẹ obinrin.

O ni awọn obinrin kii fun oun niṣẹ amọ awọn ọkunrin lo maa n gbe iṣẹ fun oun ti wọn si maa n ṣe iwuri fun oun lọpọ igba.
Fatimah ni iṣẹ POP naa ko rọrun rara, bẹẹ ni iwọsi wa nibẹ, koda, ọpọ ọkunrin lo ti sa fun oun nitori pe iṣẹ naa loun yan laayo ninu gbogbo ti obinrin le ṣe.
Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ fun ohun ti Fatimah
Sọ fun BBC Yoruba.





