Babaláwo so ọmọ rẹ̀ méjì mọ́lẹ̀, fi ebi pa wọ́n ku

Oríṣun àwòrán, Ogun Police
Ọwọ ikọ̀ Amotekun nipinlẹ Ogun tí tẹ baba kan, ẹni ọdún marundinlaadọta pé ó ṣekú pá ọmọ rẹ méjì.
Ọkunrin náà, Gbenga Ogunfadeke ni wọn fẹ̀sùn kan pe o so àwọn ọmọ rẹ mejeeji naa mọlẹ ninu yara kan eyi to sokunfa iku wọn.
Oludari ikọ̀ Amotekun nipinlẹ Ogun, David Akinremi lo sísọ loju iṣẹlẹ yii nínú atẹjade kan to fọwọ́sí nilu Abeokuta lọ́jọ́bọ.
Akinremi ni ọjọ Isẹgun ni wọn mú ọkùnrin náà nilu Ibiade tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ogun Waterside nígbà tí ìyàwó rẹ tẹ́lẹ̀ wa fi ẹjọ rẹ sun ikọ̀ náà.
Atẹjade naa ni Ogunfadeke jẹ baba ọlọmọ mẹta, to si fi ẹsun kan awọn ọmọ naa pe wọn ń jalè.
Lati igba ti igbeyawo Ogunfadeke ati iya rẹ̀, Busola Otusegun, ti forí sanpọn, tó sì ti gbà àwọn ọmọ náà sọdọ, lo tí ń fìyà jẹ wọn - Amotekun
Idi ree tí baba náà ṣe sọ wọn mọlẹ bii ẹran nínú ilé kan lai fun wọn ni omi tàbí oúnjẹ fún oṣù mẹta, eyi tó mú kí meji ninu awon ọmọ naa ku.
Ikọ Amotekun ni lati igba ti igbeyawo baba naa ati iya awọn ọmọ naa, Busola Otusegun, ti forí sanpọn, tó sì ti gbà àwọn ọmọ náà sọdọ, lo tí ń fìyà jẹ wọn.
Àwọn ọmọ naa lo jẹ Yusuf Ogunfadeke, ọmọ ọdún méjìdínlógún, Dasola Ogunfadeke, ọmọ ọdun mẹ́tàdínlógún àti merindinlogun.
"Abigbẹyin tí orí ko yọ lo pàdé àbúrò bàbà wọn obinrin nilu Ibiade, tó sì ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà fun, èyí tó ṣokùnfà ikú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ mejeeji.
O ni laarin oṣù kẹrin sì íkẹfà ọdun 2022 ni iṣẹlẹ náà wáyé lẹ́yìn tí àwọn padà lọ máa gbé nilu Ibiade láti Ijebu Ode.
Ìdí sì rèé tá ṣe lọ gbé bàbà náà ni kété tí ìyà àwọn ọmọ yìí fi iṣẹlẹ naa tó wà létí. "
"A kò rí oku ọmọ kankan níbi tí bàbá náà ni òun sìn àwọn ọmọ náà sì"
Ikọ̀ Amotekun ṣàlàyé pé nígbà táwọn ń fi ọ̀rọ̀ wá bàbà náà lẹ́nu wo, ó gba lóòótọ́ pé òun sọ àwọn ọmọ náà mọlẹ, àmọ́ irọ ni pé òun kò fún wọn ní oúnjẹ àti omi, òun sì kọ ní òun pá wọn.
O ni ọ̀na láti yọ olè jijà kúrò lójú wọn lo mu kí òun so wọn mọlẹ.
Wọn ní bàbà náà tún ṣàlàyé pé òun máa ń gbé àwọn ọmọ náà lọ sile ìwòsàn fún itọju nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn ṣàìsàn àmọ́ wọn kú lásìkò àìsàn náà.
"Àmọ́ ohun tó ń yà wá lẹ́nu nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni pé a tọpasẹ ilé ìwòsàn to ni òun máa ń gbé àwọn ọmọ náà lọ lásìkò tí wọn ba n ṣàìsàn àmọ́ a kò rí ibẹ rárá.
Bákan náà, a kò rí oku ọmọ kankan níbi tí bàbá náà ni òun sìn àwọn ọmọ náà sì níbi tó ń gbé nilu Ijebu Ode, kó tó kọ lọ silu Ibiade, ká sì gbìyànjú láti hu òkú wọn.
"Ara sì ń fu wa pé ó seese ko jẹ pe o mọọmọ pa àwọn ọmọ náà ni lati fi wọn ṣe ètùtù"
Torí pé Ogunfadeke kò fi ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ọmọ mejeeji tó mọ̀lẹ́bí rẹ kankan létí gan mú ifura lọwọ, paapaa nígbà tó jẹ́ pe babaláwo ni bàbá náà.
Ara sì ń fu wa pé ó seese ko jẹ pe o mọọmọ pa àwọn ọmọ náà ni lati fi wọn ṣe ètùtù."
Ikọ̀ Amotekun wá kéde pé wọn ti fà afurasi náà le ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun lọ́wọ́ fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí.















