LAUTECH gbégi dínà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti máa gbé mọ́tò wọ ọgbà ilé ẹ̀kọ́.

Aworan Fasiti Ladoke Akintola

Oríṣun àwòrán, others

Awọn alasẹ fasiti Ladoke Akintola niluu Ogbomoso ti gbegi dina awọn akẹkọọ lori lilo mọto ninu ọgba ile ẹkọ naa.

Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti akọwe fasiti naa, Kayode Ogunleye fi lede lọjọbọ ọsẹ yii.

Atẹjade ọhun lo tun ba awọn olukọ fasiti naa wi pe wọn ko gbọdọ lo asọ dudu fi bo ọkọ ayọkẹlẹ.

Atẹjade ọhun ni “Awọn alasẹ ile ẹkọ fasiti Ladoke Akintola ninu ipade ti wọn ṣe lọjọ kejilelogun, osu kẹta, ọdun 2023, ti pinnu lori awọn igbesẹ wọnyi.”

"Gbogbo ọkọ ayọkẹlẹ to ba jẹ ti akẹkọọ ni ko ni anfani lati wọle sinu ọgba naa mọ. Ko si aye fun mọto tí ko ba ni nọmba idanimọ.”

"Fífi asọ dudu bo ọkọ ayọkẹlẹ tí àwọn oṣiṣẹ maa n ṣe ni ko ṣe itẹwọgba mọ, ile ẹkọ yii yoo fi iya to tọ jẹ ẹnikẹni to ba ru ofin wọnyii.”

Awọn ile ẹkọ gíga miiran ti ko fi aye silẹ fun akẹkọọ lati maa gbe mọto wọ ninu ọgba

Lọdun 2021 ni fasiti ijọba apapọ ti Oye Ekiti, FUOYE, paṣẹ fun awọn akẹkọọ lati dẹkun gbigbe ọkọ ayọkẹlẹ wọle si ọgba ile ẹkọ naa.

Saaju ni ile ẹkọ gbogboniṣe, Poly ti Auchi, nipinlẹ Edo ti kọkọ gbe ofin kan naa kalẹ fun awọn akẹkọọ rẹ.

Adeyemi College of Education to wa nipinlẹ Ondo ati ile ẹkọ gbogbo nise Poly ti Delta ni Ogwashi-Uku naa pẹlu awọn ile ẹkọ gíga ti ko fi aye silẹ fun awọn akẹkọọ lati gbe ọkọ ayọkẹlẹ wọn wọle sinu ọgba ile ẹkọ.