Ìjàmbá Bọ́ọ̀sì BRT àti ọkọ̀ Danfo gbẹ̀mí Dẹ́rẹ́bà, aráàlù sọ iná sí BRT!

Ọkọ BRT to gbina l'Eko

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Eko ni wipe ọkọ akero ijọba ti wọ́n n pe ni BRT kan kọlu awọn ọkọ akero aladani meji mii ti ọpọ mọ si Danfo ni ipinlẹ Eko to si ti gbẹmi eeyan kan.

Oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo ni Eko, LASTMA ti ileeṣẹ BBC ba sọrọ lori foonu amọ ti ko fẹ ka darukọ rẹ fi aridaju han pe lootọ ni ijamba ọkọ ọhun waye to si tun sọ pe lootọ ni awakọ Danfo kan ti gbẹmi mi.

Amọ o sọ pe wọn ti gbe awọn to farapa nibẹ lọ si ileewosan fun itọju.

Awọn “Area Boys lo dana sun bọọsi – Oṣojumikoro

Ọkọ BRT to gbina l'Eko

Oríṣun àwòrán, LASTMA

Osojumikoro kan ti o mọ bi gbogbo ijamba ọkọ naa ṣe ṣalaye fun BBC pe lẹyin ti ọkọ BRT naa pa dẹrẹba ọkọ danfo tan ni awọn ọmọ adugbo jade ti wọn da ina sun ọkọ BRT naa.

Ẹwẹ, ninu atẹjade to fi ranṣẹ si awọn oniroyin, oludari ni ẹka ileeṣẹ panapana ni ipinlẹ Eko, Adeseye Margaret ṣalaye pe ileeṣẹ awọn doju kọ ijamba ina kan ni agbegbe Ifako lọna Afra 3rd Mailand Bridge.

“Wọn fi ọrọ ijamba ina naa to wa leti ni ọfiisi wa ni nnkan bii ago mẹsan abọ owurọ Ọjọru ti awọn oṣiṣẹ panapana wa to wa ni agbegbe Alausa si gbera kia lọ sibẹ.

Ijamba ọkọ

Oríṣun àwòrán, Lagos Fire Service

Wọn ba ọkọ bọọsi elero mẹrinla kan ati ọkọ BRT mii to n ku ina lara”.

Adesye ni awọn oṣiṣ awọn kan lu iṣẹ. Lasiko yii ni wọn doola ẹmi ọkunrin kan ti wọn si ti mu u fun ileeṣẹ Ọlọpaa agbegbe Ogudu.

“Ni bayii, a ti tọju oju ọna, a ti ko awọn ọkọ naa kuro ni oju popo ti awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ, LASTMA naa si ti n boju to lilọ ati bibọ ọkọ loju ọna naa lati rii pe ko si wahala kankan.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post