Atiku kí Fintiri kú oríire, Ó ní àwọn afipágbàjọba gbìyànjú ṣùgbọ́n ...

Atiku ati Fintiri n ki ara wọn

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/twitter

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, to tun jẹ oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar ti kan sara si iwọle sipo lẹẹkeji gomina Umaru Fintiri ni ipinlẹ Adamawa.

Atiku ni iṣejọba tiwantiwa lo bori ninu gbogbo igbesẹ to waye ṣaaju, lasiko ati lẹyin ibo to gbe e wọle.

Aisha ‘Binani’ Dahiru ti ẹgbẹ oṣelu APC ni alakoso INEC ni ipinlẹ Adamawa kọkọ kede lai tii pari akojọpọ esi atundi ibo gomina ni ipinlẹ naa.

Olu ileeṣẹ ajọ INEC nilu Abuja wọgile igbesẹ naa lọjọ Aiku ki o to tẹsiwaju pẹlu akojọpọ ibo ni ọjọ Iṣẹgun.

Lẹyin ti akojọpọ ibo pari lọjọ iṣẹgun ni wọn kede pe Gomina Fintiri ti ẹgbẹ oṣelu PDP lo bori.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn kede orukọ rẹ ni Atiku fi ọrọ sita pe ire bori ibi ninu eto naa.

“Mo ki Gomina Ahmadu Fintiri ku oriire ibo to gbe e wọle lẹẹkeji. Mo si dupẹ lọwọ awọn eeyan iyi ni ipinlẹ Adamawa, lọkunrin ati lobinrin, ti wọn dide tako awọn afipagbajọba ati ọta ijọba tiwantiwa.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Atiku ni ẹkọ pataki ti wọn kọ nipa iṣẹlẹ naa ni fun awọn ọmọ Naijiria lati joye oju lalakan fi n ṣọri ki wọn ma si ṣe fi aye silẹ fun awọn ọta ijọba tiwantiwa pẹlu erongba wọn lati ja ifẹ araalu gba ki wọn si yọ taya lẹsẹ ifẹ araalu lati fi ibo yan ẹnikẹni to ba wu wọn.

Atiku Abubakar wa ni ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi ibo aarẹ lorilẹede Naijiria bayii nibi to ti n tako esi ibo to gbe Bọla Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC wọle gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.