Irọ́ ni pé mo fún òṣìṣẹ́ INEC ní ₦2b láti kéde mi bíi ẹni tó borí ìbò gómìnà Adamawa – Binani

Oríṣun àwòrán, others
Oludije sipo gomina nipinlẹ Adamawa, Aishatu Dahiru ‘Binani,’ ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ laarin ilu pe oun fun aṣoju INEC nipinlẹ naa, Hudu Yunusa Ari atawọn mii ni riba ki wọn le kede oun gẹgẹ bii ẹni to bori atundi ibo gomina to waye nibẹ.
Ṣaaju ni Ari ti kọkọ kede pe Binani lo jawe olubori ninu eto idibo naa lẹyin ọga rẹ, eyii to mu ki INEC ni ọkunrin ọhun lọ rọkun nile, ti wọn si sun ikede esi ibo ọhun siwaju.
Ninu atẹjade kan ti Binani fi lede, o ni oun ko fun oṣiṣẹ INEC kankan ni riba gẹgẹ bii iroyin to n tan kalẹ.
Atẹjade naa ni “Mi o ṣe bẹẹ rara, mi o si le ṣe bẹẹ.”
“Ọrọ yii lo jade lasiko ti awọn oṣiṣẹ gomina atawọn janduku kan n fi ọpalamba iya jẹ oṣiṣẹ INEC naa.”
“Mo fẹ sọ ni gbangba pe mo ni igbagbọ ninu iṣejọba awarawa mi o si ni ṣe ohunkohun ti yoo tabuku ijọba awarawa lailai.”
“Mi o si lara awọn oloṣelu to n fi jagidijagan wa ipo oṣelu nitori mo ti kopa ninu eto idibo ri ti mo si jawe olubori sipo aṣojuṣofin ati aṣofin ri lai si wahala kankan.
Binani sọ pe awọn alagbara kan lati ilu Abuja lo mọọmọ da esi ibo naa ru.
Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ ni Adamawa ati kaakiri Naijiria fun atilẹyin wọn.
Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé sáà kejì gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa

Oríṣun àwòrán, I. Domiya
Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Umaru Fintiri, ti wọle gẹ bii gomina ipinlẹ naa fun saa keji.
Fintiri bori ibo ọhun pẹlu ibo ti iye rẹ jẹ 430,861 nigba ti ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Aisha Dahiru ni ibo ti iye rẹ jẹ 396,788.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta ti a wa yii ni eto idibo gomina ọhun waye amọ idibo naa ko kẹsẹ jari, eyii to mu ki wọn kede atundi ibo to waye lopin ọsẹ to kọja.
Eto idibo ọhun lọ ni irọwọrọsẹ ṣaaju ki aṣoju INEC nipinlẹ ọhun to kede pe Aisha Dahiru, ti ọpọ mọ si Binani lo jawe olubori, eyii to da wahala silẹ.
Amọ aṣoju ajọ INEC ni ipinlẹ ko laṣẹ labẹ ofin lati kede ẹni to jawe olubori nigba ti wọn ṣi n ka ibo naa lọwọ.
Ọpọ lo gbagbọ pe Aisha Dahiru, ti INEC kọkọ kede ṣaaju yii, ni yoo jẹ gomina obinrin akọkọ ni Naijiria, amọ o lulẹ.
Lílọ sí ilé ẹjọ́ olùdíje APC l'Adamawa kò lè dí àyípadà ìjọba lọ́wọ́ ní May 29 – Agbẹjọ́rò

Oríṣun àwòrán, other
Ọrọ di ero wa woran nibi eto idibo sipo gomina nipinlẹ Adamawa lọjọ Aiku nibi ti alamojuto ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa, Hudu Yunusa ti kede Aisha Binani gẹgẹbi gomina ti ilu dibo yan nibẹ.
Ikede naa waye lai jẹ pe eto akojọpọ ibo tii pari pẹlupẹlu bi o ṣe jẹ pe ẹni ti alamojuto ibo gomina ni ipinlẹ naa, ti ofin fun laṣẹ lati kede ibo ko ṣe si ni ijoko.
Ọrọ yii ti wa di awuyewuye, paapaa julọ lori ipo ti ofin di mu lori ọrọ naa.
Ibeere ti awọn eeyan n beere bayii ni pe ṣe ko ni si akoba fun ayipada eto iṣejọba ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un bayii.
Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Amofin Kanmi Ajibọla ṣalaye pe wahala ti ko nidi ni alakoso ajọ INEC ni ipinlẹ Adamawa fẹ da silẹ atipe ọna abayọ kan ṣoṣo lo wa fun INEC bayii, oun si ni pe ki wọn ṣe akojọpọ eto idibo naa ki wọn si kede ẹni gan an to bori ibo naa.
Amofin Ajibola ni gbigba ile ẹjọ lọ ti Binani ṣe fi ara jọ itan awọn obinrin meji to n ja fun ọmọ kan ni inu Bibeli niwaju Ọba Solomoni.
O ni lilọ ti Binani gba ile ẹjọ lọ n fihan pe ejo rẹ lọwọ ninu, o si fẹ da wahala ofin ti ko yẹ ko waye silẹ ni ipinlẹ naa ni.
Lori boya gbigbe ọrọ naa lọ si ile ẹjọ lee fa idiwọ pẹlu ayipada ijọba loṣu karun un, Amofin Ajibọla, to ti figbakan ri jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro lẹkun Ileṣa ni ipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe ko si idi lati bẹru lori eyi.
O ni ni iru iṣẹlẹ bayii ko lee da omi eto ayipada iṣejọba ru loṣu karun un ati pe gbogbo ẹjọ naa lawọn adajọ yoo tete yanju rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, irufẹ awọn ẹjọ bayii yoo tete gba amojuto to nilo ni ile ẹj lati lee bura fun oludije to ba wọle lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2023.













