Mi ò lè wo òkú ọmọ mi, wọ́n ti gún un lọ́rùn yána-yàna; ọmọ Nàìjíríà ẹ gbà mi o!

Àkọlé fídíò, Kabirat Sobola
Mi ò lè wo òkú ọmọ mi, wọ́n ti gún un lọ́rùn yána-yàna; ọmọ Nàìjíríà ẹ gbà mi o!

“Gbogbo ọmọ Naijiria ẹ gba mi o, mi o mọ Kabir ri o, to fi n bere orukọ mi ati number mi lori iku ọmọ mi, ẹ ṣaanu mi o!”

Ọgbẹni Taiwo Sobola, to jẹ baba oloogbe Kabirat Sobola ti ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ti wọn ṣadede ri oku ọmọge naa ninu yara rẹ.

Ọgbẹni Taiwo sọ pe ọna ibiṣẹ ni oun wa ki wọn to pe oun pe ọmọ naa sọnu.

BBC Yoruba gbera lọ si ilu Abeokuta ni ipinlẹ Ogun lati lọ wa kulẹkulẹ iṣẹlẹ arabinrin kan, Kabira Sobola ti wọn dede ba oku rẹ ninu yara ọrẹkunrin rẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ kede pe o di awati fun ọjọ bii melo kan.

Ẹbi Kabirat Sobola

Baba Kabira, Ọgbẹni Taiwo Sobola sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwanilẹnuwo yii pe oun wa ni ọna ile lati ibi iṣẹ ni oun gba ipe pajawiri kan pe wọn n wa ọmọ oun.

"Fọto ọmọ mi o ṣee wo fun mi rara rara nigba ti mo ri ọgbẹ ọbẹ lara rẹ, gbogbo ọmọ Naijiria ẹ ṣaanu mi o".

Arabinrin Atinuke Sobola toun naa jẹ iya Kabira pariwo sita pe ki awọn eeyan ṣaanu oun tori ọmọ oun o sọ fun oun pe oun n fẹ Kabir kankan.

Baba Kabira

Bi wọn ṣe ba oku Kabira ninu ile Kabiru to lọ fẹjọ sun ọlọpaa

Kabira Sobola

"O ṣeeṣe ko jẹ pe ọrẹbinrin mi ti gba ile ọkunrin mii lọ".

Ni ti ọrẹkunrin rẹ, Kabiru to jẹ ẹni ti wọn fura si pe o pa a, iroyin ni oun gan lo lọ fi ẹjọ iṣlẹ naa sun ni agọ ọlọpaa pe ọrẹbinrin oun ti di awati.

O fi foonu pe gbogbo awọn ọrẹ rẹ o si tun sọ fun ọlọpaa pe boya ọrẹbinrin oun ti gba ile ọkunrin mii lọ.

Lẹyin ọjọ diẹ pẹlu iwadii awọn ọlọpaa, wọn ri oku Kabira ninu yara Kabiru pẹlu ọpọlọpọ apa lara rẹ.

Wọn fi panpẹ ofin mu Kabiru fun ifọrọwanilẹnuwo igba yii si ni wọn rii wipe o mọ ọpọlọpọ nnkan nipa iṣẹlẹ naa.

Iya Kabira

Ẹwẹ, baba Kabira sọ fun BBC Yoruba pe oun n pe fun idajọ ododo lori iku ọmọ oun.

Bakan naa, awọn mọlẹbi mii atawọna ra adugbo naa ba ikọ iroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa ninu fidio yii.

Islamiyat Salaudeen to jẹ ọrẹ rẹ ti wọn jọ lọ ile ẹkọ naa kẹnu bọ ọrọ lori iru ibaṣepọ to wa laarin Kabira ati ọrẹbinrin rẹ.