Kà nípa Bíṣọ́ọ̀bù Oluwafeyiropo tó r’ẹ́wọ̀n he fẹ́sùn ìfipá bá ọmọ ìjọ rẹ̀ méjì lòpọ̀

Biṣọọbu Feyi

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ni ọjọ Kẹtadinlogun oṣu kẹrin ni wọn gbe oludasilẹ ijọ “I Reign Christian Ministry”, Biṣọọbu Oluwafeyiropo Daniel lọ ile ẹjọ lori ẹsun pe o fipaba obinrin meji (ti a ko le darukọ wọn) lopọ ninu ṣọọṣi rẹ.

Gẹgẹ bi igbẹjọ naa ṣe waye ni ile ẹjọ to n gbẹjọ nipa ẹsun ibalopọ ati ifiyajẹni to wa ni Ikeja, ipinlẹ Eko, oṣu kẹfa ọdun 2020 ni olujẹjọ da ẹṣẹ naa.

Ile ẹjọ ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Ikota Villa Estate ni Lekki, ipinlẹ Eko ti wọn si ni o lodi si abala ofin 260(2) ti ipinlẹ Eko eyi to ni ṣe pẹlu iwa ọdaran.

“Oluwa mi, mi o jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan mi”

Feyi Daniels

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Biṣọọbu naa sọ niwaju adajọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun meji ọtọọtọ ti wọn kan an bẹ si ni agbẹjọro rẹ, oluwola Oyewole beere lọwọ ile ẹjọ pe ki wọn gba beeli rẹ.

Oyewole jẹ ko di mimọ pe onibara oun san beeli eyi ti ileeṣẹ ọlọpaa fun un to si ti n farahan ni agọ wọn latinu oṣu karun ọdun 2022 to n jọwọ ara rẹ fun iwadii ọlọpaa.

Iroyin ni wọn ti kọkọ pee ko foju han nile ẹjọ amọ ti ko farahan amọ agbẹjọro rẹ sọ pe ko gbọ nipa rẹ ni.

“Gbajumọ adari ẹsin ni olujẹjọ yii jẹ o si ti fihan pẹlu iṣesi rẹ pe ko ni ru ofin ile ẹjọ rara.

Ẹsun ti wọn fi kan an yii jẹ eyi ti eeyan lee gba beeli rẹ o si ni awọn oniduro to ṣee gbẹkẹle ti wọn yoo duro fun un”. Eyi ni oun ti agbẹjọro Biṣọọbu ọhun sọ.

Agbẹjọro to dari awọn ti ijọba, Ọgbẹni Babajide Boye ti ṣaaju rọ ile ẹjọ pe ki wọn ma ṣe gba beeli rẹ.

Boye ni ẹsun ti wọn ka sii lọrun jẹ eyi to lagbara gan ti wọn ba si ṣe ohun to lee fun olujẹjọ laye, yoo gbera.

Feyi Daniels

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fi kun un pe “o tun ṣeeṣe ki olujẹjọ maa da ọgbọn si ọrọ bi igbẹjọ naa ṣe n lọ. Biṣọọbu ni to si ni oriṣiriṣi ẹka ijọ rẹ, ati pe bi wọn ba fi le gba beeli rẹ, o lee lo ipo rẹ lati fi da ọgbọn si igbẹjọ naa tori wọn mọ ọ gẹgẹ eeyan to ni aṣẹ to si tun lee da ẹṣẹ naanigba miran.

“A rọ ile ẹjọ lati ma gba beeli olujẹjọ nitori ko tii fun ile ẹjọ ni aridaju to ṣe pataki ti wọn fi lee gba beeli rẹ”, agbẹjọro fun ijọba sọ eyi.

Lẹyin ti adajọ gbọ ẹjọ igun mejeji ni adajọ Oshodi ni oun gba beeli Alufa naa pẹlu iye to to ogun miliọnu naira pẹlu oniduro meji to lagbara ati le san dede iye owo yii kan naa.

Bakan naa ni adajọ ni ki afurasi to n jẹ olujẹjọ yii ko iwe irina oke okun rẹ silẹ fun ile ẹjọ to si tun paṣẹ pe ki wọn jara mọ iṣẹ lori igbẹjọ naa.

Ko to wa di igba ti yoo ri owo beeli san pẹlu oniduro ti ile ẹjọ beere fun, adajọ ti paṣẹ pe ki wọn gbe afurasi naa, Biṣọọbu Oluwafeyiropo lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri.

Wọn ti sun ẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹsan oṣu karun ọdun yii.

Ohun to yẹ koo mọ nipa Biṣọọbu Oluwafeyiropo Daniels?

Feyi Daniels

Oríṣun àwòrán, OTHERS

  • “Oluwafeyiropo Daniels jẹ ẹni ti Jesu Kristi Oluwa wa farahan ni ojukoju ni jọ ikẹrinla oṣu kẹfa ọdun 2011 ni ilu Ido Ile, ipinlẹ Ekiti”.
  • Eyi ni akọsọ ọrọ to wa loju opo ijọ “I Reign Christian Ministry” gẹgẹ bi itan ti wọn kọ silẹ.
  • Itan naa tun ṣalaye pe ninu ifarahan ọhun ni Jesu ti sọ fun Feyi pe “tẹle mi, emi yoo si sọ ọ di eeyan”.
  • Lẹyin eyi ni itan ọhun ni pe a fi iran han Biṣọọbu Feyi pẹlu aṣẹ pe ko lọ maa ko awọ́n eniyan jọ ti yoo maa bori nile aye gẹgẹ bi Ọba.
  • Orilẹede Ghana ni ilu Accra ni Biṣọọbu Feyi ti bẹrẹ iṣẹ iranṣẹ gẹgẹ bi wọn ṣe ni Oluwa sọ fun un lodi si ilu Lekki ni Eko to ti kọkọ fẹ bẹrẹ.
  • Fun idi eyi, iṣ iranṣẹ rẹ bẹrẹ ni ọjọ kọkanla oṣu kejila ọdun 2011 ni opopona Spintex road, Accra, Ghana lati ibẹ ni ihinrere ti tan kaakiri awn apa ibomiran nilẹ Afirika.
  • Wọn ni lẹyin ọdun mẹfa gẹgẹ bi ajihinrere ni awọn gba ipe lati bẹrẹ si ni gbin ijọ kaakiri.
  • Laarin ọdun 2017 si 2019, wọn ti ni ijọ mẹtala.
  • Lọwọlọwọ, Biṣọọbu Oluwafeyiropo ni ẹka ijọ rẹ ni Naijiria ni agbegbe Opebi, Ikeja ni Eko ati agbegbe Lekki Epe Peninsula ni ipinlẹ Eko bakan naa.
  • “Wolii Ọlọrun ni mi, Wolii akọkọ ati ikẹhin too ni lati pade. Wolii si awọn orilẹede ati adari fun gbogbo agbaye. Bakan naa, oniwaasu ọrọ Ọlọrun ati olukọni nipa idokoowo ni mi”. Feyi Daniel sọ eyi funrarẹ loju opo ijọ rẹ.
Akọsilẹ Biṣọọbu Feyi lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, ireign.org