‘Èͅfoͅn tuntun tó ń fa àìsàn ibà míràn tún ti woͅ ilú’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ileesͅeͅ eto ilera ni orileͅede Ghana ti kede pe eͅfoͅn tuntun kan to n fa aisan iba ti woͅ ilu wa, eleyii ti woͅn pe orukoͅ reͅ ni Anopheles Stephensi.

Ileesͅeͅ eto ilera naa ni awoͅn se awari eͅfoͅn naa ni agbegbe Dansoman ati Tuba ni oul iul orileͅede naa, Accra.

Woͅn ni igba akoͅkoͅ ni yii ti awoͅn yoo ri iru eͅda eͅfoͅn bayii, ti woͅn sa[ejuwe reͅ geͅgeͅ bi eyi tik ii gboͅ, tik ii gba.

Amoͅ adari ajoͅ NMEP, Nana Yaw Peprah ni gbogbo eto ti wa nileͅ lati gbogun ti aisan iba yii.

Kilo mu eͅfoͅn Anopheles Stephensi lera ju awoͅn to ku loͅ

Oͅdun 2019 ni Anopheles Stephensi koͅkoͅ woͅ ileͅ Afrika, leͅyin to ti ja ranyin ni awoͅn ilu bii Ethiopia, Sudan, Somalia ati Naijiria.

Ijoͅba ileͅ Ghana ni osu Keͅta òͅun ni awoͅn koͅkoͅ keͅeͅfi reͅ, ti o si lagbara ju awoͅn oogun apa eͅfoͅn loͅ.

Ninu oͅroͅ Ajoͅ WHO, ajoͅ naa ni eͅfoͅn naa le da wahala aisan iba sileͅ ni Afrika ju ti teͅleͅ loͅ nitori atanka reͅ.

Idi ti woͅn fi n pe ni kii gbo -kii gba ni pe;

  • O ma n ja rainrain kiakia
  • O le dagba ni ileͅ to bag bona
  • Ko si agbegbe ti ko ti le soͅsͅeͅ
  • Woͅn kii tete ri pa

Bawo ni ijoͅba Ghana se feͅ kapa reͅ?

Ileeseͅ eto ilera ni Ghana ni awoͅn ti gbe igbimoͅ amuseͅya sita ti yoo ri pe ijoba bori eͅfoͅn tuntun naa.

Lara awoͅn ohun ti woͅn yoo se ni;

  • Ki woͅn ko awoͅn omi to rejoͅ si awoͅn agbegbe ile ati ilu kuro nibeͅ
  • Ki woͅn lo net apa-eͅfoͅn lati fi sun
  • Ki awoͅn ara adugbo sͅoͅra fyb adagun omi ni agbegbe naa.

Ghana ti buwoͅlu abeͅreͅ ajeͅsara aisan iba

Orileͅede Ghana ti di orileͅede akoͅkoͅ to buwoͅlu abeͅreͅ ajeͅsara aisan iba ti awoͅn animoͅ sayeͅnsi sapajuwe pe yoo soͅ igba di oͅtun

Abeͅreͅ ajeͅsara naa ni woͅn pe ni R21 to sisͅͅeͅ ju awoͅn abeͅreͅ miran loͅ lati gbogun ti aisan iba.

Ijoͅba ni awoͅn n se ayeͅwo reͅ loͅwoͅ ki awoͅn to lee fun awoͅn araalu.

Bakan naa ni ajoͅ WHO n gbe igbeseͅ lati buwoͅlu abeͅreͅ ajeͅsara naa.

O kere tan egberun loͅna eͅgbeͅta eniyan ni aisan iba n pa ni oͅdoͅoͅdun, paapaa awoͅn oͅmoͅde.