Wọ́n ti sìnkú Temitope táwọn ọlọ́kadà kan lù pa l‘Akure, ẹkún sọ!

Temitọpẹ Ọlọrunfẹmi, ọdọkunrin ti awọn eeyan kan lupa nilu Akure lọjọ diẹ sẹyin lori awawi pe ọmọ yahoo ni ti wọ kaa ilẹ sun.
Awọn mọlẹbi ati ọrẹ arakunrin naa ṣe eto isinku rẹ lọjọ Aje.
Awọn eeyan ṣe idajọ ọwọ fun Temitọpẹ lẹyin to fi ọkọ kọlu awọn ọlọkada lagbegbe Ijọka leyi to mu ẹmi ọlọkada kan lọ ti awọn mẹfa miran si tun farapa yannayanna.
Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ sọ pe ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to ba wọn peju si ibi isinku naa ni ko jẹ ki wahala miran tun bẹ silẹ nigba ti awọn ẹbi ati ọrẹ oloogbe naa gbarata lẹyin isinku rẹ ti wọn si fẹ ya bo awọn ọlọkada kan ti wọn pade lọna lasiko ti wọn fẹ lọ sin oku naa.

Ẹsun iṣẹ jibiti ori ayelujara ti ọpọ n pe ni ‘yahoo-yahoo’ni wọn fi kan arakunrin naa ki wọn to da gbẹmi rẹ.
Bakan naa ni awọn to hu iwa laabi naa tun wi pe wọn ri ijapa, posi kekere, awọtẹlẹ obirin, ọṣẹ dudu atawọn nkan miran ninu ọkọ naa, eyi ti wọn sọ pe o fihan pe oogun owo lo ṣe leyi to mu ki wọn nigbagbọ pe o mọọmọ gbẹmi awọn to kọlu ni.

Oríṣun àwòrán, other
Ọlọpaa ni afurasi meje ti wa lahamọ lori ọrọ naa

Oríṣun àwòrán, police Ondo state
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti ṣe afihan eeyan meje gẹgẹ bi afurasi lori iṣẹlẹ iku Temitọpẹ ti wọn si ti ṣalaye pe wọn yoo fi oju ba ile ẹjọ laipẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Funmi Ọdunlami-Omisanya sọ fun BBC News Yoruba pe iwadi ṣi n lọ lọwọ.
SP Ọdunlami-Omisanya tun ṣalaye pe lilu ni wọn lu arakunrin naa paa, kii ṣe pe wọn dana sun un gẹgẹbi ọpọ ileeṣẹ iroyin ti ṣe n gbe e kiri.
Iya Temitọpẹ ati iyawo rẹ ni irọ ni ọrọ yahoo-yahoo ti wọn fi kọ ọ lọrun

Oríṣun àwòrán, screenshot/twitter
Ẹwẹ, iya Temitope ati iyawo rẹ lo ti jade lati tako ọrọ ti awọn to ṣekupa ọmọ ati ọkọ wọn n sọ pe ọmọ “ yahoo-yahoo” ni.
Wọn ni ẹru iyawo ati ọmọ rẹ to fẹẹ ko lọ silu Eko lo wa lẹyin ọkọ ati pe kolo lasan ni wọn pe ni posi kekere.
Wọn tu fikun pe iṣẹ awakọ igbalode Uber ni Temitope n ṣe, kii ṣe iṣẹ gbajuẹ ori rara ayelujara.
O fikun pe awọn tọwọ ti tẹ ni yoo foju ba ile ẹjọ ni kete ti iwadi ba pari lori ọrọ naa.












