A ti mú afurasí méje nínú àwọn tó ṣekúpa Tope Olorunfemi ní Akure, wọn yóò fojú balé ẹjọ́ láìpẹ́ – Ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti sọ pe ọwọ ti tẹ meje ninu awọn to ṣekupa Tope Olorunfemi, ọdọkunrin ti awọn eeyan kan lu pa niluu Akure lori ẹsun ṣiṣẹ ‘Yahoo.’
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Funmi Odunlami Omisanyan sọ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan niluu Akure pe iwadii ti bẹrẹ, awọn afurasi naa yoo si foju bale ẹjọ laipẹ.
Odunlami sọ pe niṣe ni wọn lu oloogbe naa pa, kii ṣe pe wọn dana sun gẹgẹ bi iroyin ti awọn eeyan kan n gbe kiri.
O ni “Wọn lu u pa ni, kii ṣe pe wọn jo nina, amọ wọn jo ọkọ ayọkẹlẹ rẹ nina.”
“Ọwọ ọlọpaa ti tẹ meje ninu awọn afurasi... a n ṣe iwadii lori awọn kan, amọ awọn kan wa ti wọn kopa ninu iṣẹlẹ naa.”
“A ti ba iwadii de ibi to lapẹrẹ, ti a ba ti pari iwadii, a o gbe wọn lọ sile ẹjọ.”
Agbenusọ ọlọpaa naa sọ pe eeyan kan ṣoṣo lo ku ninu ijamba ọkọ oloogbe naa, nigba ti awọn mẹfa to farapa, ki awọn araalu to ṣekupa ọdọkunrin ọhun.
O pari ọrọ rẹ pe awọn ẹni yo mọ oloogbe naa dele wa lara awọn to lu u pa.
Ohun ti awọn afurasi sọ lagọ ọlọpaa
Nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ, awọn afurasi naa ti ọjọ ori wọn jẹ lati ogun ọdun si ọdun mejilogoji ṣalaye ipa ti wọn ko.
Ọkan lara wọn, Victor Amos ni “Nigba ti mo de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, mo ri ti wọn ti lu oloogbe naa niluu bara... mo mu okuta lati fọ mọ ni ori, mi o tilẹ mọ pe aburo ọrẹ mi kan ni.”

Ọlọpaa kọ lo mu mi, emi funra mi ni mọ jọwọ ara mi fun awọn ọlọpaa lẹyin ti awọn eeyan bẹrẹ si n pin aworan mi kaakiri ori ayelujara pe mo wa lara awọn to ṣekupa oloogbe naa.”
“Mo sọ fun ọlọpaa pe mo sọ lukota, mo si pẹlu awọn to lu u amọ emi kọ ni mo pa.”



