Ajínigbé sin ọmọ ọdún mẹ́ta láàyè lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ gba ₦150,000 owó ìtúsílẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, ISAHGAMBO/TWITTER
Ileesͅeͅ oͅloͅpaa ni ilu Katsina ni oͅwoͅ ti ba arakunrin kan ti woͅn fi eͅsun kan pe o pa oͅmoͅ oͅdun meͅta to jigbe.
Oͅmoͅ oͅdun meͅta naa ni woͅn ni arakunrin to n gbe agbegbe Sabuwar Santa, ni ijoͅba ibileͅ Musawa sin laaye leͅyin to gba owo eͅmi N150,000 loͅwoͅ baba reͅ ninu N800,000 to bere fun un.
Afurasi ajinigbe naa ti orukoͅ reͅ n jeͅ Abdulaziz ni oͅloͅpaa fidi reͅ muleͅ pe o wa ni ahamoͅ woͅn.
Agbeͅnusoͅ ileesͅeͅ oͅloͅpaa ọhun ni awoͅn ri Abdulaziz mu ni oͅjoͅ kejila, Osu Keͅrin, to si jeͅwoͅ pe lootoͅ lo n seͅ eͅseͅ naa.
Oͅloͅpaa soͅ bi isͅeͅleͅ naa ṣe waye
Ileesͅeͅ oͅloͅpaa ni Oͅjoͅ Keͅtalelogun, Osu Keͅta, ni Abdulaziz woͅ ile awoͅn oͅmoͅ naa ni oͅganjoͅ oru, to si ji oͅmoͅ naa gbe loͅ.
Oͅloͅpaa ni afurasi naa fi leͅta sileͅ to si juwe bi baba oͅmoͅ naa, Adamu Alhassan, yoo se ri oͅmoͅ naa leͅyin to ba san owo eͅmi rẹ tan.
Bakan naa lo fi noͅmba eͅroͅ ilewoͅ reͅ sileͅ.
Baba oͅmoͅ naa pe noͅmba oͅhun to si duna dura lati san N150,000 geͅgeͅ bi owo eͅmi oͅmoͅ naa, amoͅ ti oͅroͅ ko jasi ayoͅ.
Leͅyin ti oͅloͅpaa gboͅ si oͅroͅ naa ni woͅn beͅreͅ iwadii to si jeͅwoͅ pe lootoͅ ni oun ji oͅmoͅ naa gbe amoͅ ohun ti sin laaye.
Nibayii, oͅloͅpaa ni iwadii ti beͅreͅ ni peͅreͅwu ti woͅn si n gbe afurasi naa loͅ ileeͅjoͅ lati wa wi ti eͅnu reͅ.












