Bí àṣírí òní POS tó ná ₦280M tó ṣèèṣì bọ́ sí àkáńtì rẹ̀ ní Ilorin ṣe tú rèé

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Arakunrin oni POS kan ti wọ gau lẹyin to na owo ti kii ṣe tirẹ ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara.

Arakunrin naa ti wọn n pe orúkọ rẹ ní Alfa Rafiu lo n gbe agbegbe Akuko, Abayo ni ilu Ilorin.

Alfa Rafiu to ti wa ni àhámọ́ ọlọ́pàá bayii ni awọn ara agbegbe rẹ ti n woyé bi o se dede di olowo ọsan gangan tó sì n ra ile nla, ra mọto ayọkẹlẹ fún awon eniyan to tun ra awọn kan lọ Hajj kekere.

Bawo lo ṣe ṣe kòńgẹ́ adúrú owó náà?

Bi owo òhún se n wọ apo isuna rẹ ni ọsẹ meji lera lera lo n ku owo naa na.

Awọn ara adugbo rẹ ṣa n woye nipa bi o se di olowo ojiji, amọ ewe rẹ sunko nigba ti awọn banki fi ẹjọ rẹ sun olópàá.

Ara adugbo rẹ tó bá oniroyin sọrọ ti ko fẹ kí wọn darukọ rẹ ni Alfa Rafiu lo ko ara rẹ sí ìyọnu.

O ni o yẹ ki o tete lọ sọ ni banki nigba ti òun ri owo naa to n wọle sì inú àpò banki rẹ.

Agbẹnusọ fun Ileesͅeͅ oͅloͅpaa ni ipinlẹ Kwara fi idi iṣẹlẹ naa múlẹ amo o ni oun ko ni le sọrọ pupọ nipa rẹ nitori ẹka tó n gbọ ẹsun ìwà òdaran lo wa lórí ọrọ naa bayii lati ilu Eko.

‘’Ileesͅeͅ oͅloͅpaa to n ri si oͅroͅ awoͅn oͅdaran ni FCIID ni Alagboͅn-Close , Ikoyi, nipinleͅ Eko lo wa fi panpeͅ oͅloͅpaa gbe Alfa Rafiu.’’

‘’Bakan naa ni mi o ni le soͅroͅ lori isͅeͅleͅ yii nitori kii se ikawoͅ mi lo wa.’’