Wo ọmọ Nàìjíríà tó ṣe ọkọ̀ ìdíje ‘Formular 1 race car’ àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, Ọmọ Naijiria to ṣe ọkọ formular 1
Wo ọmọ Nàìjíríà tó ṣe ọkọ̀ ìdíje ‘Formular 1 race car’ àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà

Lagbaye ere ije to gbajumọ ni ere idije ọlọkọ ayarabiaṣa ‘Formular 1 race car’. Bi o tilẹ jẹ wi pe idije yii gbajumọ, kii ṣe eyi to n waye ni Naijiria tabi gbajumọ bii awọn ere idaraya bii bọọlu, ere sisa ati bẹẹbẹlọ.

Amọṣa akọṣẹmọṣẹ imọ ẹrọ nipa ọkọ titunṣe kan, Ọgbẹni Bọla Bọlarin ti bẹrẹ ṣiṣe irufẹ ọkọ yii ni ilu Ilọrin ni ipinlẹ Kwara lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Ọgbẹni Bọla Bọlarin ṣalaye pe igba ti oun lọ si orilẹede Netherlands ni oun ti kọkọ bẹrẹ si ni ni ifẹ si irufẹ awọn ọkọ ayarabiaṣa naa ti oun si ko awọn ọmọ iṣẹ jọ lati ṣe e nigba ti oun pada si Naijiria.

Ọkọ formular 1

"Ipinnu wa ni lati lo awọn ohun elo lati Naijiria nikan"

Awọn onimọẹrọ lẹnu iṣẹ

Ọgbẹni Bọlarin tun ṣalaye siwaju sii pe ipinnu awọn ni ibẹrẹ pẹpẹ iṣẹ naa ni lati rii pe ohun elo abẹle nikan ni awọn lo ki awọn le e fi ọwọ sọya pe Naijiria ni gbogbo rẹ ti wa.

O ni eyi nira pupọ nitori airi awọn ohun elo kan, sibẹ awọn lo ohun to wa ni ọja.

Bẹrẹ lati irin taya ẹnjini ati bẹẹlọ, Ọgbẹni Bọlarin ni awọn ọja ni ilu Ilọrin, awọn ọja isọ paati ọkọ, ọja ti wọn ti n ta awọn aloku irin nilu Ilọrin lawọn ti ra awọn ohun elo ti wọn lo.

Ọgẹni Bọla Bọlarin

Bakan naa lo ni irin gbe awọn de ilu Eko pẹlu lati ra awọn ẹya ara ọkọ ti awọn lo.

Amọran kan to mu wa fun awọn alaṣẹ, paapaajulọ lẹka ere idaraya ni pe ki wọn gbiyanju ati ri pe ere idaraya idije ọkọ ‘Formular 1’ gbilẹ ni Naijiria, eyi to ni yoo lee mu anfani ja wa fun awọn onimẹrọ to ba ni iran ati ṣe irufẹ awọn ọkọ bayii labẹle.

O ni eyi yoo tubọ tun bu kun owo to n wọ inu ọrọ aje orilẹede Naijiria lọdọọdun.