Mo ṣe ìlérí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìbúrawọlé, kí á lè mú ìsọ̀kan dé bá Nàìjíríà -Tinubu

Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu
Aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu ti ṣeleri lati bẹrẹ isẹ kete lẹyin ayẹyẹ iburawọle lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2023 nitori ifọwọsowọpọ orilẹede Naijiria.
Tinubu ni oun yoo ri pe ibasepọ orilẹede Naijiria ati ilẹ Amẹrika dan mọnran sii, eyi ti yoo ṣe ọpọlọpọ anfani fun orilẹede mejeeji.
Aarẹ tuntun ti wọn dibo yan ọhun sọ eyi lasiko to ba akọwe ijọba ilẹ Amẹrika, Anthony Blinken sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ tuntun, Tunde Rahman fi lede, gomina tẹlẹ ni ohun to jẹ oun logun ju ni bi ayipada to yanranti yoo se de ba igbe aye awọn ọmọ orilẹede Naijira, ti oun si setan lati pese ohun iranwọ ati igbasoke fun awọn to ku diẹ kaato fun.
O ni oun yoo rii pe oun ko tẹ oju ijọba awarawa mọlẹ, ti oun yoo fi tọkantọkan sin awọn eeyan orilẹede Naijiria gẹgẹ bii Aarẹ.
Ifọrọwerọ ohun to to ogun isẹju ni Aarẹ ti wn ṣẹṣẹ dibo yan ti rọ ijọba Amẹrika lati pese ohun iranwọ fun orilẹede Naijiria lori ọrọ eto abo to mẹhẹ ati bi ọrọ aje yoo se gbooro si.
Ninu esi rẹ, Akọwe Blinken fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ibaṣepo to dan mọran yoo wa larin Naijiria ati Ilẹ Amẹrika.
O ṣeleri lati kopa tirẹ lati rii pe ibaṣepọ naa dan mọran laarin orilẹede mejeeji.
Àwọn olùgbé ìlú Abuja pe ẹjọ́ láti dá ìbúrawọlé Tinubu dúró, wọ́n ní kí Buhari máa ṣèjọba lọ
Awọn eeyan marun un kan ti wọn n fi ilu Abuja ṣe ibugbe ti pe adajọ agba Naijiria ati olori awọn adajọ ni Naijiria lẹjọ lori ẹsun pe wọn kede Bola Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria ti awọn araalu dibo yan.
Ninu ipẹjọ ọhun to waye lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun yii, wọn ni Tinubu kuna lati ni ida 25% iye ibo ti wọn di niluu Abuja.
Awọn olupẹjọ ọhun, Anyaegbunam Okoye, David Adzer, Jeffrey Ucheh, Osang Paul, ati Chibuike Nwanchukwu ni awọn pe ẹjọ naa lorukọ ara awọn ati lorukọ awọn olugbe ilu Abuja.
Wọn ni awọn n fẹ ki ile ẹjọ ṣalaye ohun to wa ninu abala 134(2)(b) ninu iwe ofin Naijiria to sọrọ nipa ẹni ti yoo jawe olubori ninu idibo Aarẹ ati ipa ti ida 25% iye awọn olugbe ilu Abuja yoo ko ninu esi ibo ọhun.
Awọ olupẹjọ naa ni awọn tun n fẹ ki ile paṣẹ ki Aarẹ Muhammadu Buhari ṣi wa lori oye titi ti ofin yoo fi sọ ẹni gan ti ipo Aarẹ naa tọ si.
Gẹgẹ bii iwe ipẹjọ wọn ṣe sọ, wọn ni ki ile ẹjọ wọgile iwe ẹri moyege ti INEC fun Tinubu gẹgẹ bii Aarẹ ti ilu dibo yan.
Ati pe ki adajọ agba Naijiria maṣe burawọle fun Tinubu titi ti igbẹjọ naa yoo fi pari.
Tinubu, to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu idibo Aarẹ Naijiria to waye ninu oṣu Keji ọdun yii pẹlu ibo ti iye rẹ le ni miliọnu mẹjọ.
Ẹwẹ, ajọ INEC ti sọ pe kii ṣe dandan ki oludije ni ida 25% ibo ti wọn di niluu Abuja ko to jawe olubori bii Aarẹ, nitori ilu Abuja ko ni ipo kankan to tayọ awọn ipinlẹ to ku ni Naijiria gẹgẹ bii awọn eeyan kan ṣe n sọ.












