Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tẹ́lẹ̀ rí lu ìyàwó rẹ̀ títí tó fi dákú rọngbọndan; Bí ọwọ́ ọlọ́pàá ṣe tẹ̀ ẹ́ nìyí

Handcuffs

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu abẹṣẹkubiojo kan to ti fẹyinti, Moses Olapade.

Eredi igbesẹ naa ko ṣẹyin bi ọkunrin ọhun ṣe lu iyawo rẹ titi to fi daku rọngbọndan.

Iroyin ni ẹni ọdun mẹrindinlọgọta naa lu iyawo rẹ nilu bara lẹyin ti obinrin naa kọ lati fun ni rimootu ẹrọ amohunmaworan wọn.

Yatọ si pe o jẹ abẹṣẹkubiojo tẹlẹ ri, ọkunrin naa tun maa n wa ọkọ ajagbe.

A gbọ pe ile wọn to wa lagbegbe Oke Aro, nilu Akure ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn alabagbe wọn lo gba obinrin naa lọwọ ọkọ rẹ ọhun lẹyin ti awọn ọmọ wọn ke gbajare si awọn eeyan adugbo lati wa doola iya wọn lọwọ baba wọn.

Awọn alabagbe naa sọ pe ṣe ni wọn ba obinrin ọhun nilẹ to ti daku rọngbọnadan, eyii to mu ki wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan.

Lẹyin naa ni wọn fi ọrọ ọhun to awọn agbagba adugbo leti, ti awọn naa si fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.

Ọkunrin naa ti wa lagọ ọlọpaa bayii nigba ti iyawo si n gba itọju nile iwosan.