Afurasí 'ọmọ yahoo' fi ọkọ̀ pa akẹ́kọ̀ọ́ tó n ṣe WAEC lọ́wọ́ nílùú Akure

Ọdọmọkunrin kan ti fi ọkọ pa ọmọ ile ẹkọ girama niluu Oba Ile, nijọba ibilẹ ariwa Akure, nipinlẹ Ondo.
Ọsan ọjọ Aje ni ọdọmọkunrin naa, tawọn eeyan fura si pe o jẹ onijibiti ori ẹrọ ayelujara, fi ọkọ ayọkẹlẹ Lexus kọlu ọmọdebinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Glory ni opopona kan ni ilu naa.
Ọdọmọbinrin ọhun ni awọn ara adugbo sọ pe o n ṣe idanwo aṣekagba nile ẹkọ girama, amọ ti ọkọ naa lọ ba nibi to ti fẹ gun ọkada nigba to n pada sile lati ile ẹkọ rẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun akọroyin BBC Yoruba pe, awakọ naa ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ n sa ere asapajude, eyi to mu ko padanu ijanu ọkọ rẹ to fi lọ gbẹmi oloogbe naa.
Lẹyin to pa ọmọdebirin naa, wọn ni ọkọ ọhun takiti lọpọ igba to si fo si odikeji opopona onibeji ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.
Awọn to wa nitosi lo doola ẹmi awakọ naa ati ọmọbinrin kan ti wọn fura pe o jẹ ọrẹbirin rẹ, ti wọn jọ wa ninu ọkọ ọhun.
Wọn gbe wọn lọ si ile iwosan nitori ifarapa ti wọn ni ninu iṣẹlẹ naa.
Ko pẹ ti wọn yọ wọn kuro ninu ọkọ, ti ọkọ ọhun gbina funra rẹ nitori ipalara to ti baa lakoko to n takiti.
Awọn oṣiṣẹ ajọ ọlọpaa ni wọn waa gbe oku ọmọdebirin naa lọ ile igbokusi.
Agbarijọ igbiyanju awọn oṣiṣẹ ajọ ologun, ọlọpaa ati ẹṣọ abo oju popo lo da alaafia pada si agbeegbe naa ni bi awọn ọdọ kan ṣe fẹẹ di oju popo pa lati dẹkun irinna ọkọ.












