‘A fún Tinubu di May 29 láti kéde àwọn dúkìá rẹ̀’

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ Code of Conduct Bureau, CCB ti kede pe aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, igbakeji rẹ ati awọn gomina mejidinlọgbọn to wọle gẹgẹ bi gomina ni di ọjọ mejilelogun lati wa kede ohun ini wọn.
Awọn miran ti wọn dibo yan to fi mọ awọn ṣẹnetọ naa ni wọn yoo kede ohun ini wọn.
Agbẹnusọ fun ajọ CCB, Abilekọ Veronica Kato ti ni jijẹwọ ohun ini wọn pẹlu eto iburawọle fun awọn ti wọn dibo yan.
O ni ọpọlọpọ awọn ti wọn dibo yan naa lo ti wa gba fọọmu ikede ohun ini ẹni ni awọn olu ile iṣẹ wọn ni awọn ipinlẹ ni Naijiria.
Awọn ti yoo ma kede ohun ini wọn naa ni awọn oṣiṣẹ pataki fun aarẹ, gomina mejilelọgbọn ati awọn aṣofin ni ijọba ibilẹ ati ti ijọba apapọ, to fi mọ awọn alaga ijọba ibilẹ pẹlu.
Ajọ naa ni ki kede naa tẹlẹ ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.
Iwe ofin Naijiria fi lede pe gbogbo oṣiṣẹ ijọba ni yoo kede awọn ohun ini rẹ kete ti wọn ba ti bẹrẹ iṣẹ ijọba wọn ati lẹyin saa wọn ni ipo.
Labẹ ofin naa, ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ lo ṣeesẹ ki wọn yọọ ni ipo, ki o si ma lee di ipo miran mu lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni ajọ ọhun fikun un pe ẹnikẹni to ba kọ lati kede ohun ini rẹ ni wọn ko ni bura wọle fun.
Wọn fikun un pe ofin Naijiria paṣẹ pe ọkan lara eto iburawọle ni ki awọn ti wọn ba dibo yan kede awọn ohun ini wọn.












