Iná ẹlẹ́tíríìkì ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ní Sudan bó ṣe ń bá ilé ìwòsàn tún iná ṣe

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK ALA DANEDN
Akẹkọọ onimọ ẹrọ kan ni orilẹede Sudan nibi ti ogun ti n lọ lọwọ ti kagbako iku ojiji lasiko to n ba ileewosan kan lara awọn to faragba nibi ogun naa tun ina ṣe.
Muhammedin Fadul Idris Wadi ti awọn ọrẹ rẹ mọ si Ala Danedn, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa to n kọ ẹkọ imọ oju ẹrọ ni Sudan wa lara ẹgbẹ kan to kora jọ lati ṣeranwọ fun ileewosan naa lati lee tẹsiwaju itọju fun awọn eeyan.
“O fi aye rẹ silẹ gẹgẹ bi ẹni to n sin awọn eeyan”, Ahmed Ishaq to n kẹkọọ pẹlu rẹ ni Fasiti Fasher sọ fun BBC.
Lara ọrọ kan ti Fadul kọ si oju opo Facebook rẹ ni: “Ma duro de anfani, pese rẹ funra rẹ”.
Lati igba ti wahala ti bẹ silẹ ni Sudan laarin ẹgbẹ ologun meji lọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹrin ni ẹgbẹ rẹ ti wọn ko ara jọ gẹgẹ bii ọdọ al-Thawra (Youth of the al-Thawra Initiative) lati maa ran awọn eleto ilera lọwọ ni Fasher, olu ilu ipinlẹ North Dafur.
Eyi n waye nitoripe o fẹrẹ to gbogbo ileewosan ayafi ọkan, South Hospital ti wọn mọọmọ fi ji fun awọn iyalọmọ to di titi pa nitori bi wọn ṣe sunmọ ibi ija to n waye tabi latari bi awọn oṣiṣẹ ko ṣe le ri ọna de ibi iṣẹ.
“Mo ri i to n ṣiṣẹ pẹlu gbogbo akitiyan rẹ lati tọju awọn to farapa ni ileewosan South Hospital ni gbogbo ọsẹ akọkọ ti ija bẹ silẹ”, Ọgbẹni Ishaq sọ eyi.
O ni o tun mu inu awọn dun pẹlu gbogbo wahala ti wọn n doju kọ lakoko naa.
Wọn ni ẹgbẹ rẹ lo da owo jọ fi ra ounjẹ, ogun atawọn nnkan iranwọ ilera mii ti wọn tun ṣe atunṣe ibudo eto ilera Sayed al-Shahada ti awọn to n jagun ṣe ikọlu si lasiko ogun naa ti awọn oṣiṣẹ si ti pa iṣẹ ti.
Ile iwosan naa bẹrẹ iṣẹ pada ni ọjọ Aje ọsẹ to kọja pẹlu iranlọwọ awọn oluranlọwọ eleto ilera mẹẹdọgbọn atawọn araalu ọgọrin to jọwọ ara wọn lati ṣe iranwọ amọ sibẹ sibẹ, o tun koju wahala.
Gẹgẹ bi ko ṣe si ina ọba ni ọpọlọpọ agbegbe orilẹede naa tori ogun, Ala Danedn n ba wọn so ina ẹlẹtiriki kan to yọnu ni ileewosan ọhun nirọlẹ Ọjọba ni ina ba gbe e.
Ọrẹ rẹ ni o ṣubu wọọ silẹ lẹyin ti ina ọhun gbe e wọn si gbe e digba digba lọ ileewosan South Hospital.
Amọ lẹyin wakati mejidinlaadọta, awọn oluranlọwọ eleto ilera to wa nibẹ ko ribi doola rẹ, akẹkọ naa si ku ni alẹ Ọjọ Abamẹta.
“A ti jọ sọ fun ara wa pe lẹyin ogun yii, a o tun pade ni aarin gbungbun ilu, a o si parọ awọn ohun iro ibọn pẹlu awọn orin aladun ati ayọ”, Ọgbẹni Ishaq sọ bẹẹ.
“Amọ Ala Danedn ti lọ bayii, a si jẹ ẹ ni mimu ileri taa jọ ṣe ṣẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ oluranlọwọ lati lee mu igbe aye rọrun fawọn eeyan wa”.
Lọwọlọwọ́, awọn ologun ati awọn ẹgbẹ afarajologun RSF ṣi n doju ogun kọ ara wọn lori taa ni yoo gbajọba lawọn apa ibi kan ni olu ilu orilẹede naa, Khartoum eyi si ti ṣakoba ati ipalara fun ọgọọrọ eeyan ni orilẹede Sudan to fi mọ awọn ara orilẹede miran to n gbe nibẹ lara eyi ti awọn ọmọ Naijiria wa.















