Ohun tí Tinubu gbọ́dọ̀ ṣe nìyíí ní kété tí wọ́n bá tí búra wọlé fún un – Adeboye sọ̀rọ̀ sókè

Oríṣun àwòrán, Others
Adari ile ijọsin Redeem Christian Church of God, RCCG, Pasitọ Enoch Adeboye ti fi ọrọ ranṣẹ si Aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Bola Tinubu lori ohun to gbọdọ ṣe ni kete ti wọn fa ti bura wọle fun gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.
Adeboye ninu ọrọ rẹ rọ Tinubu lati mu awọn ileri rẹ ṣẹ fun awọn ọmọ Naijiria lori ireti orilẹede tuntun to ṣeleri fun wọn..
O ni awọn ọmọ Naijiria nilo orilẹede ti wọn yoo fi yangan, ti ireti wọn ko si ni jasi ofo lori orilẹede Naijiria.
''Asiko ti to lati fopin si iṣoro to n koju alaafia ati idagbasoke orilẹede Naijiria''

Oríṣun àwòrán, Others
Baba Adeboye ninu ọrọ rẹ ni ijọba to n bọ naa gbọdọ mu gbogbo ileri to ṣe fun awọn ọmọ Naijiria ṣe lasiko ipolongo eto idibo ni Naijiria.
O ni yatọ si iyẹn, Aarẹ naa gbọdọ wa ọna abayọ si iṣoro to fa ifaṣẹyin fun alaafia ati idagbasoke ni Naijiria.
Adari ijọ RCCG ti oṣiṣẹ pataki rẹ, Pasitọ Dele Balogun sọju fun, lo waasu bẹẹ nibi eto isin idupẹ to waye ninu ijọ Throne of Grace ni Ebute-Metta, nipinlẹ Eko.
Amọ o fikun un pe awọn adari naa gbọdọ ni ibẹru Ọlọrun ki gbogbo igbeṣẹ wọn to le jasi rere fun awọn ọmọ Niajiria.
Bakan naa lo ke si awọn ọmọ Naijiria lati gbadura fun ijọba tuntun naa pe ki Edua ran wọn lọwọ lati ṣe eleyii to dara fun Naijiria, ki orilẹede naa si so rere ni asiko yii.
Adari naa wa kesi awọn ọdọ lati mu iṣẹ to dara ni okunkundun, ki wọn ṣọra fun iwa ipa, iwa ọdaran ati ẹgbẹ okunkun,ki wọn si tun ṣọra fun ifẹ owo.












