Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yà bàrá ṣekúpa èèyàn mẹ́jọ míì ní Texas

Oríṣun àwòrán, NEWSNATION VIA CBS
Eeyan mẹjọ tí padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ ayọkẹlẹ kan rọ lu wọn nibudokọ kan to sunmọ ile awọn ọmọ alianiya ati arin irinajo Texas.
Iṣẹlẹ naa lo waye niluu Brownsville, lẹnu ibode si orilẹede Mexico, ni dede ago mẹjọ abo alẹ ana.
O to eeyan marun-un miiran to tun farapa yanayana níbi iṣẹlẹ naa.
Awakọ naa ni ọwọ ti tẹ, ti yoo si foju ba ile ẹjọ.
Ileeṣẹ Ọlọpaa Brownsville ni awọn ko tii le sọ bi iṣẹlẹ naa se waye ati pe boya awakọ ọhun mọmọ kọlu awọn eeyan naa ni.
Saaju ni ileeṣẹ iroyin lorilẹede Amẹrika ti kọkọ sọ pe iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han awakọ naa mọmọ kọlu awọn eeyan naa ni.
Oludari ibudokọ Bishop Enrique San Pedro Ozanam, Victor Maldonado sọ fun BBC pe pẹlu ere asapajude ni ọkọ ayọkẹlẹ naa ba de ibi ibudokọ ọhun.
Maldonado ni ki iṣẹlẹ naa to waye, o to ogun eeyan to wa nibi ibudokọ ti wọn n duro de ọkọ ti yoo gbe wọn.
O ni pupọ ninu awọn eniyan to padanu ẹmi wọn lo wa lati orilẹede Venezuela.
"Emi ati awọn osisẹ mi n gbinyanju lati mu mọra ni," Maldonado sọ pẹlu omije.
"Pupọ awọn eeyan ọhun lo jẹ iya to ni ọmọ kekere lọwọ, to fi mọ awọn ọkunrin niwaju wọn bayi, wọn dẹ padanu ẹmi wọn.”
Lẹyin ijamba naa, ileeṣẹ ọlọpaa gbe awakọ naa lọ si ile wosan lati lọ ṣe ayẹwo boya o n lo ogun oloro ṣugbọn iroyin ni ko fi ọwọ wẹ ọwọ pẹlu awọn ọlọpaa.















