Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn darandaran lọ pá aláboyún, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ méjì sílé l’Osun? Àbọ̀ ìwádìí wá rèé

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Radio
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn kan tó gba ìgboro pé àwọn darandaran kan ṣekúpa ìdílé kan run.
Ìròyìn tó gba orí ayélujára ni pé àwọn Fulani darandaran kan yawọ ile ìgbé obìnrin olóyún kan ní Idi-Ogungun, Iragbiji, ní ìjọba ìbílẹ̀ Boripe, ìpínlẹ̀ Osun.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni wọ́n ní àwọn darandaran náà gba ẹ̀mí lọ́rùn olóyún ọ̀hún, ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ wọn méjì.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti wá jáde láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn tí wọ́n ń gbé kiri náà.
Ọlọpaa fidi okodoro ohun to waye mulẹ
Àtẹ̀jáde tí agbenusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Yemisi Opalola fi léde ní ìjàm̀bá ọkọ̀ kan ló wáyé ní ọjọ́ Kejì, oṣù Karùn-ún ní nǹkan bí í aago mẹ́sàn-án alẹ́ ku ìṣẹ́jú márùn-ún.
Opalola ní agbègbè Idi Ogun un ní ẹ̀gbẹ́ ìlú Onioba, Iragbiji ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá náà èyí tó wáyé láàárín ọkọ̀, ọ̀kadà àti àwọn màlúù kan.
Ó ṣàlàyé pé awakọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Babatunde Afeez tó wa ọkọ̀ Toyota Camry kan ló lọ kọlu ọ̀kadà Bajaj, èyí tí Oladapo Saheed wà.
Agbenusọ ọlọ́pàá náà ní Oladapo Saheed tó wa ọ̀kadà náà ló gbé ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn méjì sórí ọ̀kadà kí ìjàm̀bá náà tó wáyé nígbà tí awakọ̀ náà ń sá fún àwọn màlúù.
O ni “Àwọn màlúù kan ló ya wọ orí títì lásìkò tí àwọn awakọ̀ àti ọlọ́kadà náà ń bá eré bọ̀.”
“Nígbà tí awakọ̀ náà gbèrò láti yà fún àwọn màlúù náà ni ó lọ kọlu àwọn tí wọ́n wà lórí ọ̀kadà ọ̀hún”
Opalola ní ojú ẹsẹ̀ ni ọmọ kan nínú àwọn ọmọ méjì tó jẹ́ ọmọkùnrin tí Oladapo Saheed gbé sórí ọ̀kadà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Bákan náà ló ní Saheed Oladapo, ìyàwó rẹ̀ tó wà nínú oyún náà jẹ́ Ọlọ́run nípè ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú.
Ó fi kun pé ọmọ wọn kan tó ṣẹ́kù tó jẹ́ obìnrin ṣì wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ báyìí.
Ó ní ọwọ́ ṣìkún òfin ọlọ́pàá ti tẹ awakọ̀ àti darandaran tó ni àwọn màlúù tó fa ìjàm̀bá náà.
Ó ṣàlàyé pé ní kété tí ìwádìí bá ti parí ni àwọn yóò gbé àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé ẹjọ́.
Bákan náà ló ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá bá àwọn ẹbí àwọn olóògbé náà kẹ́dùn, pé kí Ọlọ́run fún wọn ní ẹ̀mí láti gba àdánù wọn.












