Agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ ní Texas, èèyàn mẹ́jọ jáde láyé, ọ̀pọ̀ farapa yánayàna

Texas Shooting

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọkùnrin agbébọn kan ti ṣekúpa ènìyàn mẹ́jọ ní ilé ìtajà kan níùú Dallas, Texas, l’Amẹrika.

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ fara gba ọta, tí wọ́n si ti wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú bayii.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni wọ́n sá kúrò ní ilé ìtajà náà lẹ́yìn tí àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn ní ṣàdédé ni ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn mọ́ àwọn èrò tó ń kọjá.

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti ṣekúpa agbébọn náà àti pé ó dàbí wí pé ó dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni.

Lára àwọn tí ọkùnrin náà ṣekúpa ni àwọn ọmọdé wà nínú wọn.

Ọ̀gá iléeṣẹ́ panápaná Allen, Jonathan Boyd ní ènìyàn méje tó fi mọ́ agbébọn náà ló papòdà ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀, tí àwọn méjì mìíràn sì tún gbé ẹ̀mí mì ní ilé ìwòsàn.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Allen, Brian Harvey ní ọlọ́pàá kan ló gbọ́ ìró ìbọn tó sì lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Harvey ní ọlọ́pàá náà ló kojú agbébọn ọ̀hún tó sì borí rẹ̀.

Agbẹnusọ ilé ìwòsàn ní àwọn tó fara gbọta ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùn-ún sí mọ́kànléláàdọ́ta.

Gómìnà Texas, Greg Abbott júwe ìṣekúpani náà gẹ́gẹ́ bí àdánù ńlá àti pé àwọn ti ṣetán láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn aláṣẹ abẹ́lé.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Amẹ́ríkà ti rọ àwọn ènìyàn tó bá ní fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́wọ́ láti kàn sí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, FBI bí wọ́n ṣe ń gba ẹ̀rí jọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní aṣọ dúdú ni agbébọn náà wọ̀ láti òkè délẹ̀ tí wọ́n sì bá ìbọn AR-15 lára rẹ̀ lẹ́yìn tó kú tán.

Fídíò tó jáde láti ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàfihàn bí àwọn ènìyàn ṣe ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Kò dín ní ènìyàn 105,000 tó ń gbé ní Allen tó wà ní máìlì ogun sí àríwá Central Dallas.

Ẹni tó bá ti pé ọdún mọ́kànlélógún ní Texas ló ní àǹfàní láti lo ìbọn ní Texas láìní ìwé àṣẹ àyàfi tí onítọ̀hún bá ti sẹ̀wọ̀n rí.

Ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní ọdún yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn 198 ló ti wáyé níbi tí ó kéré tán ènìyàn mẹ́rin pàdánù ẹ̀mí tàbí farapa.

Ẹnìkan tó wà ní ilé ìtajà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, Fontayne Payton sọ fun ilé iṣẹ́ ìròyìn AP pé ṣàdédé ni òun n gbúròó ìbọn lásìkò tí òun ra ọjà lọ́wọ́.

Ó ní nígbà tí òun ń jáde kúrò nínú ilé ìtajà ọ̀hún, òun rí òkú àwọn ènìyàn nílẹ̀.

Mayor Allen, Ken Fulk ní ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ fún àwọn tó sì kan sáárá sí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti àwọn panápaná fún akitiyan wọn.

Sẹ́nétọ̀ Texas, John Cornyn nínú àtẹ̀jáde kan lórí Twitter ní òun bá àwọn ènìyàn Allen kẹ́dùn.