Portable ra ọkọ̀ Brabus G-Wagon tí iye owó rẹ̀ tó ₦‎150m, ó ní Ọlọrun ni àṣírí òun

Portable

Oríṣun àwòrán, portablebaeby

Gbajugbaja olorin takasufe, Habeeb Okikiola ‘Portable’ tun ti fi ọkọ bọgini tuntun mii kun ara awọn ọkọ rẹ to ni tẹlẹ.

Portable, Gẹgẹ bii iṣe rẹ, lo kede ọrọ naa loju opo Instagram rẹ, to si n sọ pe Ọlọrun ni aṣiri oun.

O fi awọn aworan ọkọ bọgini dudu naa ati fidio lede, to si n sọ pe ki awọn ololufẹ oun ba oun yin Ọlọrun logo fun ọkọ ọhun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, Ọlọrun kii dojutini, ore ọrẹ Ọlọrun si loun n jẹ.

O sọ pe “Ẹyin eeyan mi, ẹ ba mi yin Ọlọrun logo o... Zazuu!”

“Mo wa dupe, Ọlọrun lo n ṣe, Ọlọrun mi kii doju tini, mọto awọn OG ni mo n lo bayii ooo.”

Portable tun kede pe ileeṣe to n ta ọkọ naa ni yoo gbe wa ba oun nile.

Lẹyin naa ló da owo fun awọn ololufẹ rẹ to peju siwaju ileeṣe to n ta ọkọ naa nibi ti ọpọ awọn ololuifẹ rẹ ọhun ti n pari “Zazuu... wahala wahala.”

Gẹgẹ bii atẹjade ileeṣẹ to n ta ọkọ ayọkẹlẹ niluu Eko, Carmart, wọn ni iye owo ọkọ Brabus G-Wagon naa ko din ni ₦‎150m si ₦‎240m, amọ iye owo rẹ da lori ọdun ti wọn ṣe ọkọ ọhun, ati pe boya tuntun ni abi tokunbọ.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹnu ọjọ mẹta yii ni Portable foju bale ẹjọ lẹyin ti ọkan lara awọn alabaṣe rẹ tẹlẹ, Manny Monie fẹsun kan an pe o fi ọwọ ọla gba oun loju.

Awọn ọlọpaa gbiyanju lati fi ṣikun ofin mu Portable lasiko naa amọ o kọ jalẹ, eyii to mu ki wọn fi awọn ẹsun mẹfa kan an ko to foju bale ẹjọ.