Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà tún ti ṣèkìlọ̀ fáwọn olóṣèlú tó fẹ́ da ìṣèjọba Tiwantiwa rú

Oríṣun àwòrán, muhammadu buhari/twitter
Ileeṣẹ ologun ni Naijiria tun ti kilọ fun gbogbo awọn arijẹnidi madaru to n gbero lati pagidina eto igbejọ fun aarẹ tuntun, Bọla Tinubu ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un.
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun ni Naijiria ṣalaye pe digbi lawọn ologun wa lati rii daju pe eto naa, ti yoo waye ni nnkan bi ọjọ mẹrinlelogun si asiko yii, lọ ni irọwọ rọsẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọmọogun alabo Naijiria, Ọgagun Musa Danmadami gbe ikilọ naa kalẹ nilu Abuja.
Bakan naa ni olori ijọba ologun lorilẹede nigbakan ri lorilẹede Naijiria, Yakubu Gowon pẹlu n gba awọn oloṣelu lamọran pe ki wọn tẹwọ gba abajade yoowu to ba ti ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye esi ibo aarẹ jade wa.
Ileeṣẹ ọmọogun Naaijiria ni gbogbo igbesẹ yoowu to lee fẹ waye lati yi eto iṣejọba tiwantiwa lagbo da sina lawọn yoo tẹ mọlẹ.
Bakan naa ni ọgagun agba ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ, Faruk Yahaya pẹlu ti kọkọ ṣekilọ pe gbogbo awọn ti wọn ba kẹfin pe o fẹ da omi alaafia orilẹede Naijiria laamu lawọn yoo fin lata.
Bakan naa lo ṣe ikilọ fun awọn ọmọ ikọ IPOB atawọn ẹgbẹ agbebọn ESN gbogbo pe ki wọn maṣe gbiyanju ati gbe ina wo oju awọn ologun ti wọn ko ba fẹ rugi oyin.
Awọn oloṣelu kan to padanu lasiko ibo to kọja ti n fi apap janu tako eto ibura fun aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan, ti wọn si n pe fun iṣejọba fidihẹ. .
Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni gbogbo ipa lawọn yoo sa fun eto naa lati lọ ni irọwọrọsẹ.
APC, PDP kan sara si igbesẹ ileeṣẹ ologun
Ẹgbẹ oṣelu APC ti kan sara si ileeṣẹ ọmọogun Naijiria fun ifọkansin wọn lati daabo bo eto iṣejọba tiwantiwa.
Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu APC, Bala Ibrahim ni oun ko ri ohun to buru ni gbajare ti ileeṣẹ ologun ke sita naa.
O ni gbogbo ohun to ba fẹ ti igi boju iṣejọba tiwantiwa lawọn tako nitori kii ṣe oogun diẹ lawọn ọmọ Naijiria la ki eto iṣejọba tiwantiwa to dohun lorilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ tirẹ, alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Debọ Ologunagba pẹlu kan sara si ileeṣẹ ọmọogun, amọṣa o ni ko yẹ ki wọn sọ aṣiri ohun ti wọn fẹ ṣe sita fun aye gbọ.
O ni nṣe lo yẹ ki wọn rọra dide mu gbogbo awọn to ba n gbero ati pagidina eto iṣejọba awarawa lorilẹede Naijiria ni.












