Ukraine fẹ́ sekúpa ààrẹ Putin ni wọ́n se ju àdó olóró sí Kremlin- Russia

Aworan

Orilẹede Russia ti fi ẹsun kan ijọba orilẹede Ukraine wi pe wọn gbiyanju lati pa aarẹ Vladimir Putin ni wọn se ju ado oloro si gbungbun aarin ilu Moscow.

Ileeṣẹ aarẹ ni irinse idaabobo lo ja ado oloro drone meji duro ni aarin oru.

Agbẹnuso fun Putin ni aarẹ naa ko si ni inu ile naa nigba ti wọn ju ado oloro sibẹ.

Awọn aworan lori ayelujara ti a ko le fi idi rẹ mulẹ pe ohun to jọ bi bọọlu, ko to di pe o dun pau.

Amọ aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymr Zelensky ti ni kii se orilẹede oun lo wa lẹyin ikọlu naa.

‘’A ko se ikọlu si aarẹ Putin abi Moscow. Ohun ti a n ja fun ni orilẹede wa ati ilẹ wa. A n da abo bo awọn ilu kereje ati awọn ilu nla lorilẹde naa.

Aarẹ Ukraine naa sọ eyi lasiko to n se ibẹwo si orilẹede Finland.

Amọ olubadamọran fun ilẹ Ukraine kan sọ fun BBC pe o seese ko jẹ pe Ukraine n gbiyanju lati se ikọlu nla si Ukraine.

Igba akọkọ kọ niyii ti orilẹede mejeeji yoo ma fi ẹsun kan ara wọn lori ikọlu laaarin orilẹede Ukraine ati Russia.

Osu Keji, ọdun 2022 ni orilẹede Russia sekọlu si Ukraine, ti ogun si ti bẹ silẹ laarin orilẹede mejeeji lati igba naa.