Ààrẹ Buhari lọ sí U.K. láti kópa níbi ayẹyẹ Ìwúyè Oba Charles III

Oríṣun àwòrán, MuhammaduBuhari/Facebook
Aarẹ Muhammedu Buhari yo tẹkọ leti lọ si ilu Oba loni lati pade awọn adari Orilẹede miran ti yo pejọ nibi ayẹyẹ ifinijọba Charlse III ati iyawo rẹ Camilla ni ilẹ Geesi .
Ayẹye ifinijọba ọhun ni yoo waye lọjọ kẹfa osu karun,ọdun yi.
Ṣaaju ayẹyẹ ifinijoye naa,awọn olori orilẹede Commonwealth yo sẹ ipade pọ pẹlu adari ajọ ọhun lọjọ karun osu karun ọdun yii lati jiroro lori ipa awọn ọdọ orilẹede Afrika nini ajọ Commonwealth.
Awọn to kọwọ rin pẹlu aarẹ Buhari ni,Akọwe agba fun orilẹede yii,Boss Mustapha,minisita fun ilẹ okere,Geoffrey Onyeama,Minisita fun ẹka iroyin ati asa Lai Mohammed,oludamoran fun ijọba lori ọrọ abo,Ọgagun fẹyinti Babagana Monguno,Ọga agba ajọ ọtẹlẹmuyẹ,Ahmed Rufai Abubakar,Abike Dabiri ati awọn lọgalọga ijọba Buhari











