Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ adarí àjọ INEC ní Adamawa tó sá pamọ́ lẹ́yìn awuyewuye àtúndì ìbò gómìnà

Oríṣun àwòrán, other
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ adari ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ni ipinlẹ Adamawa, Hudu Yunusa Ari.
Ọwọ awọn ọlọpaa tẹ Ọgbẹni Hudu Yunusa Ari nilu Abuja gẹgẹbi alukoro apap ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muyiwa Adejọba ṣe sọ lọjọ Iṣẹgun.
Iṣẹlẹ yii n waye lẹyin ti Ari sọ lori ifọrwerọ kan pẹlu BBC pe oun yoo jọwọ ara oun silẹ lẹyin ọsẹ meji to ti fi ara pamọ.
“Mo maa jọwọ ara mi silẹ fun awọn ọlọpaa. Ṣaaju asiko yii, ko si iwe ipe kankan ti mo ri lati ọdọ awọn ọlọpaa, amọ bayii mo ti ri iwe ipe wọn, n o si fi ara mi han laipẹ”
Adari ajọ INEC nipinlẹ Adamawa naa ṣalaye pe oun ko kabamọ kikede ti oun kede Aisha ‘Binani’Dahiru ti ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi olubori idibo gomina ni ipinlẹ naa.
Hudu kede Binani gẹgẹbi gomina nigba ti eto ibo ko tii pari ni Adamawa
Awuyewuye bẹrẹ si ni wọ tọ Ari lẹyin lẹyin atundi ibo gomina to waye ni ipinlẹ Adamawa ni ọjọ karundinlogun oṣu kẹrin ọdun 2023 nigba to fi kede Binani gẹgẹbi ẹni to bori ibo gomina nibẹ laijẹ pe akojọpọ esi idibo naa ti pari.
Igbesẹ naa lo mu ki olu ileeṣẹ ajọ INEC o wọgile igbesẹ rẹ gbogbo ti wọn si paṣẹ fun pe ko lọ rọkun nile.

Oríṣun àwòrán, screenshot
Lẹyin eyi ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari paṣẹ pe ki iwadii to rinlẹ o waye lori ọrọ naa paajulọ adari ajọ INEC naa atawọn adari ẹka ileeṣẹ abo gbogbo to wa pẹlu rẹ lasiko to ṣe ikede ọhun.
Lẹyin o rẹyin ni ajọ INEC pari akojọpọ esi idibo gomina naa ti wọn si kede gomina ipinlẹ naa Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹbi ẹni ti awọn eeyan ipinlẹ Adamawa dibo yan fun saa keji.
Lati igba yi wa ni ẹnikẹni ko ti mọ ibi ti adari ajọ INEC naa wọlẹ si lẹyin ti awọn ẹṣọ alaabo gbogbo ti n wa a.












