Àlàyé ọgá NAFDAC rèé nípa Indomie tí àwọn kàn ló léwu fún ara

Oríṣun àwòrán, NAFDAC
Ọga agba ajọ to n mojuto ipese ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria NAFDAC ti tu kẹkẹ ọrọ lori iroyin to gbode pe ajọ naa ti fofin de tita ounjẹ aladun nii Indomie Noodles.
Oludari ajọ naa ọjọgbọn Mojisola Christianah Adeyeye sọ fun BBC pe Indomie ti wọn peelo rẹ ni Naijiria ko lewu fun jijẹ araalu tori naa awọn ko fofin de.
Amọ ṣa o ni eleyi to n ti ilẹ okere wa lawọn ko faaye gba ni Naijiria rara ati rara.
Alaye yi n waye lẹyin ti awọn araalu bẹrẹ si ni kesi NAFDAC ko wa wọrọkọ fi ṣada lori iroyin pe awọn ẹda Indomie kan n fa aisan jẹjẹrẹ sara awọn to n jẹ.
Ọjọgbọn Adeyeye ni awọn ko ṣẹṣẹ gbe ofin yi kalẹ ni paapa eyi to niṣe pẹlu awọn ounjẹ to n bọ lati ilẹ okere.
Ko si nkankan to kan wa pẹlu Indomie lati Taiwan
Alaye pataki kan to tun ṣe fun akọroyin wa ni pe Naijiria ko lọwọ si kiko noodles Indomie wọle lati Taiwan tabi lati orileede miran.
O ni lati ibẹrẹ pẹpẹ lawọn ti buwọlu pipeelo Indomie ni Naijiria ti eleyi si wa ni ibamu pẹlu ofin.
''A gbe igbesẹ yi ki a baa le mojuto ipeelo noodles yi labẹlẹ ati ki awọn eeyan ti wa naa ba le riṣẹ labẹ ileesẹ to n peloo rẹ''
''Bi ẹ ba de oju opo ileeṣẹ Customs Naijiria, ẹ o ri pe wọn ko faaye gba gbigbe ounjẹ Indomie Noodles wọle lati ilẹ okere''
Ọga NAFDAC tẹsiwaju pe awọn yoo bẹrẹ si ni kaakiri lati ṣe ayẹwo lori ẹda noodles miran to wa lode ki wọn bee le mọ awọn ti wọn gbe wọle lọna ẹburu.
''Kii ṣe Indomie nikan la o maa ṣe ayẹwo rẹ bi kii gbogbo awọn to n peloo Noodles bi ti ileeṣẹ Indomie.''
Kẹmika wo gaan ni wọn lo lewu to wa ninu Noodles?
Awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria kan gbe iroyin jade pe ileeṣẹ Indofood to n peelo Indomie ti ko awọn ọja wọn kan kuro lori igba lorileede Malaysia ati nilu Taiwan.
Leyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe sọ pe awọn ri kẹmika ti wọn pe orukọ rẹ ni ethylene oxide ti wọn lo le fa ewu aisan jẹjẹrẹ.
Iroyin yi lo mu ki awọn araalu Naijiria ke si ajọ NAFDAC pe ki wọn ko Indomie to wa lori igba ni Naijiria naa nilẹ.
Amọ ṣa, Ọga ajọ NAFDAC sọ pe ko si ootọ ninu iroyin pe awọn tio fofin de jijẹ tabi tita Indomie ni Naijiria.
Adeyeye ṣalaye pe awọn kan ṣi oun gbọ ni pẹlu bi wọn ṣe ni oun s pe wn fofin de Indomie ni Naijiria.
''Kiko Indomie wọle lati ilẹ okere la ko faramọ. Eleyi ko si jẹ nkan tuntun. O ti pẹ ti ijọba ti s pe ki wọn ma ko Indomie noodles wọle lati ilẹ okere bi kii se pe ki wọn maa pese rẹ labẹle ni Naijiria.''












