N kò fìgbà kankan wà ní àtìmọ́lè nílùú London- Peter Obi

Oríṣun àwòrán, @PEter Obi
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi ti ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin kan to gba orí ayelujara pe oun dero atimọle ni ilẹ UK.
Lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan, Obi salaye pe ohun to waye ko ju ayẹwo awọn ẹsọ ibode lọ, ti gbogbo ayẹwo naa ko si ju ogun isẹju lọ.
Isẹlẹ yii ni wọn lo waye lasiko ti gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra naa tẹkọ leti lọ si London fun ọdun ajinde.
Oludari eto ipolongo fun ibo aarẹ fẹgbẹ oselu Labour, Diran Onifade lo sisọ loju ọrọ yii fawọn akọroyin ninu atẹjade kan to fisita.
Obi tẹsiwaju pe wọn da oun duro nitori pe wọn kẹfin pe eeyan fẹ lọ orukọ oun wọle.
"Wọn dami duro fun ayẹwo ni ilẹ UK nitori pe wọn kẹfin pe eeyan kan lo idanimọ mi. Wọn ko fi igba kankan dami duro.
"Tọwọ Tọwọ ni wọn fi bami sọrọ lo si abala àwọn eeyan pataki. Gbogbo rẹ ko ju ogun isẹju lọ."
‘’ Àwoͅn tó yapa kúrò ni ‘Labour Party’ ń sͅisͅéͅ tako ìpèͅjóͅ Peter Obi ni ’’

Oríṣun àwòrán, Twitter/Peter Obi
Eͅgbeͅ oselu Labour Party ti ke gbajare pe igun Lamidi Apapa ni eͅgbeͅ osͅelu Labour Party naa n sise tako ipejoͅ ti oludije sipo ssreͅ leͅgbeͅ oselu Labour, Peter Obi pe tako idibo to gbe aareͅ ti woͅn seͅseͅ dibo yan woͅle.
Ninu ateͅjade ti agbeͅnusoͅ fun eͅgbeͅ oselu Labour, Obiora Ifoh fi lede ni Oͅjoͅ Iseͅgun ni woͅn ti fi ero woͅn han
Ifoh ni woͅn t fi oͅwoͅ osi juwe ile fun Apapa to jeͅ geͅgeͅ bi igbakeji alaga eͅgbeͅ naa.
Amoͅ Apapa kede ara reͅ geͅgeͅ bi alaga eͅgbeͅ leͅyin ti ileeͅjoͅ giga ni Abuja ni ki Alaga eͅgbeͅ, Julius Abure loͅ roͅkun nile.
Lamidi Apapa feͅ da eͅgbeͅ oselu Labour Party ru ni
Eͅgbeͅ oselu Labour ni ko si oͅroͅ ninu ohun ti Lamidi Apapa soͅ pe ki woͅn da gbogbo eͅjoͅ ti eͅgbeͅ naa pe tako eto idibo sipo aareͅ nu ati awoͅn ipeͅjoͅ miran.
Woͅn ni ki ileeͅjoͅ da ipeͅjoͅ naa nu nitori woͅn ti le Lamidi ati Samuel Akingbade, Gbenga Daramola, Anselem Eragbe ati Abayomi Arabambi kuro ninu eͅgbeͅ.
Agbeͅnusoͅ fun eͅgbeͅ oselu Labour naa ni ki ajoͅ Tribunal to n gboͅ eͅsun to niise peͅlu eto idibo naa ma koͅbi ara si leͅta ti woͅn ba koͅ si woͅn tako ipeͅjoͅ Peter Obi.
Peter Obi to dije du ipo aareͅ ni oͅdun 2023 lo gba ileͅeͅjoͅ pe lori eͅsun pe oun ko faramoͅ esi idibo to gbe Bola Tinubu ti eͅgbeͅ oselu APC wole geͅgeͅ bi aareͅ.
Eͅgbeͅ oselu Labour ni eleyii fihan pe ihuwasi woͅn n tako eͅgbeͅ oselu naa, ti woͅn si feͅ da eͅgbeͅ naa ru.
Bakan naa ni woͅn wa kesi ileesͅeͅ oͅloͅpaa, DSS ati ajoͅ to n gbogun ti iwa jeͅgudujeͅra ni Naijiria, EFCC nitori woͅn feͅ doju eto oselu tiwantiwa boleͅ.















