Ènìyàn kan kú, ọ̀pọ̀ farapa bí àwọn afurasí darandaran ṣe ṣèkọlù sáwọn àgbẹ̀ ní Ondo

Oríṣun àwòrán, Collage
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àgbẹ̀ kan, Olaoluwa Olorunfemi, ẹni àádọ́ta ọdún pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ sọ́wọ́ àwọn agbébọn kan.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Olufunmilayo Odunlami-Omisanya fi léde ní ọjọ́ Ajé ní wọ́n ṣá ọkùnrin náà ní àdá pa títí ẹ̀mí fi bọ́ lọ́rùn rẹ̀.
Odunlami-Omisanya ní nǹkan bíi aago márùn-ún kọjá ogún ìṣẹ́jú ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan tí wọn kò mọ̀ wọ́n yawọ oko àwọn ọkùnrin náà ní Ifeloduro ní ìpínlẹ̀ náà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣoro.
Ó ní àwọn ènìyàn ọ̀hún tún gba fóònù àti àwọn ohun ìní àwọn àgbẹ́ mìírà tó wà nínú oko náà kí wọ́n tó pa Olorunfemi.
Ó fi kun pé lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú àwọn ẹbí Olorunfemi lọ síbi oko náà láti lọ gbé òkú rẹ̀ tí wọ́n sì gbe lọ sí ilé ìgbókùúpamọ́sí.
Bákan náà ló ní ènìyàn mẹ́jọ mìíràn tún farapa nínú ìkọlù náà.
Ẹ ṣàánú wa, wọ́n ti fẹ́ pa wá tán - Àwọn ará ìlú figbe ta
Agbẹnusọ agbègbè Ago-Oyinbo, Samuel Olowolafe ti wá ké gbàjarè sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo láti tètè bá àwọn wá nǹkan ṣe sí bí àwọn darandaran ṣe ń yawọ oko àwọn tí wọ́n ń gbẹ̀mí lọ́rùn àwọn ènìyàn àwọn.
Olowolafe ní ìkọlù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sá kúrò ní ilé ìgbé wọn nítorí ìbẹ̀rù pé kí àwọn darandaran náà tún má wà ká àwọn mọ́lé.
Ó ní ohun tí òun rò ni pé àwọn darandaran náà ń ṣe ìkọlù sí àwọn nítorí pé àwọn kò jẹ́ kí wọ́n máa da ẹran wọ inú oko àwọn.
Bákan náà ló fi kun pé ìgbà kejì rèé nínú ọdún yìí tí àwọn darandaran náà máa ṣe ìkọlù sí àwọn tó sì ní irúfẹ́ ìkọlù yìí ti ṣaájú wáyé nínú oṣù Kẹta ọdún.
Olowolafe wá rọ gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Rotimi Akeredolu láti jọ̀ ọ́ jàre wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá sí ọ̀rọ̀ àwọn kí àwọn darandaran náà tó tún wá ṣe ìkọlù mìíràn sí àwọn.
Ó ní inú ewu ni ẹ̀mí àti dúkìá àwọn tó wà ní agbègbè Powerline àti go-Oyinbo ní Ala Forest Reserve wà báyìí.















