Spain ṣetán láti hú òkú olórí ikọ̀ apàṣe wà á, Primo de Rivera

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orílẹ̀ èdè Spain ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti hú òkú olórí ikọ̀ kan tó ṣe agbátẹrù ikọ̀ apàṣẹ wà á Franco.
José Antonio Primo de Rivera ṣe ìdásílẹ̀ ikọ̀ Falange tí wọ́n sì sin òkú rẹ̀ sínú ọgbà ńlá tí wọ́n ń sin òk;u sí kan èyí tí olórí ikọ̀ mìíràn kọ́ sí ẹ̀yin odi Madrid.
Primo de Rivera jẹ́ ọ̀kan gbòógì sí ìjọba Gen Francisco tó fa ìfaǹfà èyí tó fa ogun abẹ́lé Spain láàárín ọdún 1936 sí 1939.
Itẹ́ òkú San Isidro tó wà ní Madrid ni wọ́n máa sin òkú rẹ̀ sí báyìí, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbésẹ̀ ìjọba láti lòdì sí ikọ̀ apàṣẹ wà á.
Ní ọdún 2019 ni wọ́n gbé òkú Franco kúrò ní itẹ́ náà èyí tó bí ọ̀pọ̀ àwọn alákatakítí tí wọ́n ṣì ní ìrántí rẹ̀ lọ́kàn.
Ṣíṣe ìsìnkú yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ ìjọba láti ṣe ìdádúró ṣíṣe ìgbélárugẹ èrè àwọn ikọ̀ alákatakítí yìí nínú ogun abẹ́lé náà.
Itẹ́ òkú yìí ni wọ́n ń yí padà ní ìràntí gbogbo àwọn tó bá ogun lọ yàtọ̀ sí àwọn alákatakítí yìí.
Ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹbí àwọn Primo de Rivera ni wọ́n máa sín in sín.
Ní oṣù Kọkànlá ọdún 1936 ni wọ́n fi ẹ̀yìn rẹ̀ ti àgbá látọwọ́ ìjọba Republican ní Alicante.
Primo de Rivera jẹ́ ọmọ bíbí Miguel Primo de Rivera tí òun náà jẹ́ apàṣẹ wà á èyí tó ṣe ìjọba Spain láàárín ọdún 1923 sí 1930.















