Mi ò ní ẹ̀mí láti gbé pẹ̀lú ìyàwó mẹ́fà láàfin Ooni – Olorì Silekunola

Naomi Silekunola

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Olorì tẹ́lẹ̀ rí láàfin Ooni Ile-Ife, olorì Naomi Silekunola ti ní òun kò lè padà sí ààfin mọ́ láti máa jẹ́ olorì Ọba Enitan Ogunwusi Ojaja II.

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tí olorì Silekunola ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Punch ló ti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.

Nígbà tí wọ́n ń bi í léèrè bóyá pé ṣé ó le padà sí ààfin Ooni, olorì Naomi Silekunola ní òun kò rò wí pé òun le gbé pẹ̀lú àwọn obìnrin mẹ́fà tí wọ́n jẹ́ alágbára obìnrin.

Ó ní ènìyàn jẹ́jẹ́ ni òun nítorí náà òun kò lè wà nínú ààfin pẹ̀lú àwọn olorì púpọ̀ àti pé òun kò lè gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀.

Àsìkò ọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tí ojú mi rí ní ààfin ń bọ̀

Olorì Naomi Silekunola ní àsìkò ọ̀rọ̀ kò ì tíì tó nípa gbogbo nǹkan tí òun là kọjá gẹ́gẹ́ bí olorì láàfin Ooni tí Ile-Ife.

Ó ní àmọ́ ìgbé ayé nínú ààfin gẹ́gẹ́ bí olorì jẹ́ èyí tó kún fún adùn àti ìkejì rẹ̀ ṣùgbọ́n òun kò ì tíì ní ìmísí láti sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.

“Mo gbà wí pé àwọn ìrírí kan wà láti fi kẹ́kọ̀ọ́ ni, lásìkò yìí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí mi nínú ààfin jẹ́ ohun tí mo gbọ́dọ̀ fi sínú ná.”

“Tí àsìkò bá tó láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ náà fún gbogbo ayé, Ọlọ́run máa fún mi ní ìmísí láti lè fi sọ àwọn nǹkan náà jáde, tí mà á sì ṣàlàyé gbogbo rẹ̀.”

“Gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nígbà tí mo wà ní ààfin ni mò ń ṣe àmúlò wọn báyìí pàápàá bí òun ṣe pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún lókè eèpẹ̀.

Ó ní òun gbà pé òun wọ ààfin nígbà tí òun kò mọ nǹkankan tó sì jẹ́ wí pé ayé kò gbà bẹ́ẹ̀ pàápàá ní ààfin àti pé ènìyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ akínkanjú, tó sì ní ìgboyà tó bá fẹ́ kógo ààfin já.

Inú mi máa ń dùn tí mo bá rántí pé mo bí àrẹmọ fún Ooni

Naomi ati Ooni

Oríṣun àwòrán, Instagram

Olorì Silekunola ní ọmọ òun ni àgbà ìyànu ńlá tó ṣẹlẹ̀ sí òun jùlọ nínú ọgbọ̀n ọdún tí òun ti wà láyé.

Ó ní òun kò mọ nǹkan tí òun ṣe fún Ọlọ́run tó fi fọmọ náà ta òun lọ́rẹ nítorí ológo ọmọ ni ọmọ náà jẹ́ àti pé òun ṣì máa sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ láìpẹ́.

Ó fi kun pé ọmọ òun, Tadenikawo, jẹ́ nǹkan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ń bínú òun àmọ́ òun gbà pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú òun nítorí òun lọ fi ọmọ náà ta òun lọ́rẹ.

“Tí wọ́n bá gba gbogbo nǹkan lọ́wọ́ mi, wọn ò lè gba adé orí mi nítorí ọmọ mi ni adé orí mi, ẹ má pè mí ní olorì tàbí Ayaba, Iya Oba ni kí ẹ máa pè mí.”

Mi ò káàbámọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn ìgbésẹ̀ mi

Naomi Silekunola

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Ó ní lọ́pọ̀ ìgbà tí òun bá sọ fún àwọn ènìyàn pé òun kò káàbámọ̀ lórí àwọn ìgbésẹ̀ tí òun ti gbé láti ọgbọ̀n ọdún tí wọ́n ti bí òun sáyé, àwọn ènìyàn máa ń rò wí pé òun ń gbéraga ni.

Olorì Silekunola ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí òun ni òun ti fi kẹ́kọ̀ọ́ nítorí náà òun kò kó àbámọ̀ nípa àwọn ìrírí ayé òun.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó yẹ kó ti tẹ òun rì ni òun ti là kọjá àmọ́ tí òun ṣì wà dìgbì nítorí náà kò sí ìdí tí òun yóò fi máa kó àbámọ̀ rárá.

Ó ní gbogbo ìgbésẹ̀ òun ni Ọlọ́run ti máa ń se àánú òun àti pé òun ni òpó tí òun fi ẹ̀yìn tì.

Olorì Silekunola fi kun ọ̀rọ̀ pé òun tún ṣetán láti gba ìfẹ́ láàyè nínú ọkàn òun àti pé ìyàwó tó ku díẹ̀ kó wọ aṣọ ìgbéyàwò ni òun báyìí.

Ó ní ìgbà díẹ̀ báyìí ló kù kí ìròyìn tó lágbára nípa ìgbéyàwó jáde lórúkọ òun.