Ẹ̀yin ọmọ Naijiria ni Sudan, ẹ ṣì dúró sọ́hun o! Ìdí tá ò fi lè kóo yín wálé lásìkò yìí rèé – Ijoba
''Ẹ gbà wá, ohun tí à ń là kọ́já ní Sudan kọjá àfẹnusọ''

Oríṣun àwòrán, NANSS/FACEBOOK
Awọn ọmọ orilẹede Naijiria to jẹ akẹkọọ ni orilẹede Sudan ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ lati wa ọna gbe awọn kuro lorilẹede Sudan bi ija laarin ikọ ologun Sudan ati ti ẹgbẹ RSF ṣe n tẹsiwaju.
Ija naa lo ti bẹrẹ lọjọ karundinlogun ọdun yii, ti ọpọlọpọ awọn eniyan sì ti padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ ọhun.
Adari awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ orilẹede yii, Abubakar Babangida nigba ti oun ba ileeṣẹ BBC sọrọ sọ wi pe gbogbo nkan lo nira pẹlu í ija ọhun ti ń gbona gírígírí.
Abubakar ni" lọwọlọwọ bayii gbogbo ile iwe lọ wa ni titipa, awọn ile itaja ko si ni sisi,ko si ina mọnamọna, bẹẹni ko si omi, inu ile ni gbogbo wa wa, ti ẹru si n ba wa".
"Awọn akẹkọọ Nàìjíríà ní Sudan sọrọ sókè!
Adari awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ orilẹede yii ni Sudan ni" bi awọn ọkọ ofurufu ologun ti ń fo kọja ni a un gbo ti iro ibọn si tun n dun lakọlakọ bí a ti saa sinu ile wa".
Abubakar ni awọn fohun ransẹ si aṣoju orilẹ-ede yii to wa ni Sudan ṣugbọn wọn ti fesi,ó ni awọn orilẹ-ede alawo dudu bi Uganda,ti ń gbe igbesẹ lati dola ẹmi awọn ọmọ ilu wọn.
O ni ko ti si akọsilẹ kankan wi pe ọmọ orilẹ-ede yi ti padanu ẹmi rẹ ninu rogbodiyan ọhun,o si rọ ijọba apapọ lati tete da awọn pada silẹ ki rogbodiyan ọhun to kọja afarada.
Lọwọlọwọ bayii igun Rapid Support Forces (RSF) ti kede isinmi lẹnu ija fun ọjọ mẹta.
Bakan naa ni awọn orilẹede bii Amẹrika, Ilẹ Gẹẹsi ti n ko awọn eniyan wọn kuro ni orilẹede Sudan.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Alaga ajọ to n ri si ọrọ awọn Naijiria to wa loke okun, Honorebu Abike Dabiri-Erewa ti fesi lori ọrọ awọn akekọọ ọmọ Naijiria to wa ni orileede Sudan ti wọn ti n pariwo pe ki ijoba Naijiria wa gba awọn.
Abike Dabiri jẹ ko di mimọ pe ko ni ṣeeṣe ki awọn ko awọn ọmọ Naijiria to wa ni orileede Sudan wale bayii pẹlu bi ogun se n sele lọwọlọwọ to si n pa awọn araalu lara to fi mọ awọn ara ile okere to n gbe nibẹ.
Dabiri ni bo tilẹ jẹ pe awọn ti n se eto lati jẹ ki wiwa sile wọn wa si imuṣẹ, amọ kii ṣe lọwọlọwọ yii.
Ija to n waye ni Sudan ti gba ẹmi eeyan to to irinwo bayii to si ti jẹ ki ọpọlọpọ farapa lati igba to ti bẹrẹ ni ọjọ Abamẹta to kọja laarin awọn ikọ ogun orisi meji ti ọkan wa lẹyin ọgagun Fattah al-Burhan ati igbakeji rẹ, Mohammed Hamdan Daglo to n dari ikọ afarajologun ti wọn n pe ni Hemeti.
Ki nidi?
Ninu atẹjade kan to fi si oju opo Twitter rẹ lọjọ Eti, Abike Dabiri ni iṣẹlẹ to buru jai to n waye ni Sudan yii gan lo mu ko nira ti ko si ni ṣeeṣe lati lo ọkọ baalu kankan lasiko yii.
O ni: “Nigba ti ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria ati ọfiisi orilẹede Naijiria to wa ni Sudan ti gbe awọn eto to yẹ kalẹ, ko si ọkọ baalu kankan bayii ti ko lewu lati wọ”.
O sọ siwaju pe gbogbo ọkọ baalu to wa ni papakọ ofurufu lonii ni wọn jo nina, isede tun wa lode nibẹ bẹẹ si ni ko si ọkọ baalu kankan to le ṣiṣẹ”.
Dabiri ṣalaye pe awọn egbe ẹlẹyinju aanu ti n se akitiyan lati pin ounjẹ, omi ati nnkan ilera nigba ti wọn si tun n se akitiyan lati mu ki awọn ikọ to n jagun dawọ ogun naa duro.
“Ọkan wa ati adura wa wa pelu awọn eeyan wa to wa lọhun ati gbogbo orilẹede naa.














