A kìí ṣe oní jìbìtì ní'lé Akuji, Mòlẹ́bí Alfa Ràfíu oní POS tí wón sèèsì fi N280m ránsẹ́ si àkántì rẹ̀ n'Ilorin fi igbe ta!

Agbo ile AKuji

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awon molebi Alfa Rafiu Issa, oni POS ni Ilorin tii ṣe olu ilu ipinle Kwara ti pariwo sita wipe ko si eni ti o le sọ okodoro ọrọ nipa isẹlẹ bi wọn ṣe wa fi ọlọpaa gbe Rafiu toripe o na owo ti banki ṣeesi fi ranṣẹ si akanti rẹ.

Wọn sọ fun BBC Yoruba pe afi ti awon agbofinro ba pari iwadi ti wọn n ṣe lọwọ nipa rẹ.

Alfa Rafiu Issa ti ile Agunji, Abayawo, Ilọrin ti won fi esun kan wipe o kọ lati fito awon ọlọpaa tabi banki leti nipa owo N280m ti banki kan ṣeeṣi fi ransẹ si akanti rẹ ti o si bẹrẹ si n na owo naa ni o ti wa ni ati mole bayi.

Ikọ BBC Yoruba se iwadi lọ si agbo ile wọn ti won si ni anfani lati ba awon mẹrin ọtọọtọ, ọkunrin meji ati obirin meji ti won jẹ molebi rẹ sọrọ, ṣugbon won kọ jalẹ lati sọ orukọ wọn.

Ọkunrin kan ti o jẹ okan lara awon abenugan ile naa sọ wipe ko si eni ti o mọ ekunrẹre tabi ojulowo ọrọ naa wipe amulumọla ati iroyin ẹlẹjẹ ni awon eniyan n gbe kiri.

Ile Rafiu

O sọ wipe ile Akunji ko ni akọsile jibiti bo ti wu o kere mo ri ninu itan Abayawo, bẹẹ sini Alfa Rafiu ti an sọrọ rẹ yi ni

O tun fi lede wipe Alfa Rafiu ko ko ọrọ jọ ninu ile rẹ afi ibusun ti o fi n sun ati awon ohun pẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, o sọ pe o jẹ eniyan to dara ti o si jina si iwa janduku.

Bakan naa, o sọ wipe ko si ẹni to ni "statement of account lọwọ ti o fi le sọ iye owo to wọle si akanti Alfa Rafiu, oni koda, awon ọlọpa paapa ko nii lọwọ.

O sọ wipe ohun to selẹ yi ṣe ni ni kayefi gan awon idile si n ṣe iwadi tiwọn gẹgẹ bi awọn ọlọpaa naa ṣe n ṣe iwadi.

Awọn obinrin ile Rafiu da si ọrọ

Ẹwẹ, awọn obirin ile naa ti wọn jẹ bi aburo si Alfa Rafiu sọ wipe bọda awon kii ṣe ole ati pe owo ti o wọle si akanti rẹ jẹ gẹgẹ bi bi ifa ti ko si si eniyan ti ko ni wọ loju.

Wọn ni eeyan onirẹlẹ ni Alfa Rafiu ti kii si lu jibiti, o tẹ pele mọọ wipe bi ọrọ owo naa ṣe jẹ, o ye Ọlọrun. Wọn gbadura pe ki Ọlọrun ko yọ ọ ninu ọfin to ko si yii.

Iwadii fihan pe Alfa oni POS ni iyawo ati ọmọ

Ile Rafiu

Iwadi naa jẹ ka mọ wipe Alfa Rafiu Issa ni iyawo kan pelu ọ̀mo mẹta ti iyawo rẹ si wa ninu oyun ọmọ ẹlẹẹkẹ rin lọwọlọwọ.

BBC Yoruba ba Alukoro ajo Ọlọpa ipinlẹ Kwara, Okasanmi Ajayi sọrọ, o wipe iru owo bẹẹ kii ṣe ifa rara wipe oyẹ ki o kan si banki to ṣe aṣiṣe naa lati daa pada.

O tun sọ wipe, ajọ ọlọpa kii ṣe oṣisẹ banki lootọ , “iye owo ti banki ba gbe sita ni irufẹ isẹlẹ bẹẹ ti a si rii daju pe otitọ ni, ni a o fi lede fun awon eniyan.

Agbenusọ fun ajọ naa rọ awọn ọmọ Naijiria lapapọ lati jẹ ọmọ orilẹede rere, ki wọn si ma ṣe fi ohun ti kii ba ṣe tiwọn mọ tiwọn.