Olówó fi owó ra eyín ikú - Portable figbe ta torí ìlera tó dé bá a

Portable

Oríṣun àwòrán, Portable

Gbajumọ olorin takasufe, Habeeb Okikiola Portable ti ke gbajare nipa inira to de ba latari irin to ko si eyin rẹ.

Portable ninu fidio kan to fi lede lori ikanni Instagram rẹ sọ pe irin ti oun fi obitibiti owo ko si eyin n ni oun lara.

O tun sọ pe ko rọrun lati maa kọ orin pẹlu eyin ọhun.

"₦420,000 ni mo fi ko irin si eyín amọ inira lo ba de fun mi"

Fidio ibi to ti sọrọ naa lo ti gba gbogbo ori ayekujara kan bayii.

O ni “Eyin n ro mi, ẹ ma pa mi fawọn to ni mi... Olowo fi owo ra eyin iku.”

“Mo ti ra eyin to fẹ ṣeku pa mi bayi... mi o le fi eyin naa kọ orin, o ti wa doju ẹ bayii.”

Portable ti kọkọ sọ ṣaaju pe owo ti iye rẹ to ₦420,000 loun fi ko irin naa si eyin amọ inira lo ba de fun oun.

Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede bayii lẹyin to ṣe eyin naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe eyin naa ko rẹwa lawọn mii n sọ pe eyin ọhun ba lara mu gẹgẹ bii idamu adugbo to jẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post