Àwọn èèyàn tó ti kú lẹ́yìn tí oníwàású ní kí wọ́n febi pa ara wọn láti pàdé Jesu wọ 73

Oríṣun àwòrán, Reuters
Mínísítà fétò ààbò orílẹ̀ èdè Kenya, Kithure Kindiki yóò ṣe àbẹ̀wò sí igbó Shakabola ní Malindi, ẹkùn àríwá Kilifi níbi tí wọ́n ti hú òkú ènìyàn mẹ́tàléláàdọ́rin tí wọ́n fi ebi pa ara wọn dójú ikú.
Oníwàásù kan, Paul Mackenzie ti ìjọ Good News International Church ló ní kí àwọn ènìyàn máa fi ebi pa ara wọn dójú ikú kí wọ́n le pàdé Jesu.
Ní báyìí, àwọn ọlọ́pàá ti ṣàwàrí òkú ènìyàn mẹ́tàléláàdọ́rin, tí wọ́n sì ní ó ṣeéṣe kí wọ́n tún rí jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìwádìí.
Ilé ìgbókùúpamọ́sí tó wà ní agbègbè náà ni ibẹ̀ ti kún fọ́fọ́ báyìí tí wọ́n sì ti ń ṣètò láti máa gbé àwọn òkú náà lọ sí àwọn ìlú tó súnmọ́ ibẹ̀.
Ìrètí wà pé àwọn ẹbí àwọn ènìyàn tó ti kú náà yóò yọjú síbẹ̀ lónìí láti wá ṣe ìdámọ̀ àwọn ènìyàn wọn.
Bákan náà ni ìgbàgbọ́ wà pé àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣì ń fi ebi pa ara wọn lọ ṣà wà ní agbègbè náà tí wan fi ara pamọ́ sí nínú ọgbà tó tó ẹgbẹ̀rin éékà.
Ìjọba ti kéde ààyè náà gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìwà ọ̀daràn ti wáyé tí ìwádìí sì ń tẹ̀síwájú lórí rẹ̀.
Ẹnìkan tí wọ́n tún nawọ́ gán bíi igbákejì oníwàásù náà pé òun ló máa ń sin àwọn tó bá ti kú sínú sàárè náà ti ń káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá.
Ààrẹ pàṣẹ láti fòfin gbé oníwàásù Paul Mackenzie
Ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya, William Ruto ti pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fi òfin, kí wọ́n sì fi ìyà tó tọ́ jẹ alùfáà ìjọ kan tó ní kí àwọn ènìyàn máa fi ebi pa ara wọn dójú ikú.
Ààrẹ Ruto ní agbéṣùmọ̀mí ni oníwàásù náà pẹ̀lú bó ṣe ní kí àwọn ènìyàn ọ̀hún máa fi ebi pa ara wọn kí wan le pàdé Jesu.
Àṣẹ ààrẹ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá ṣàwárí òkú ogójì ènìyàn nígbà tí wọ́n hú ilẹ̀ tí wọ́n sin àwọn ènìyàn náà sí.
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, Japhet Koome àti olórí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn Kenya, Mohamed Amin náà wà lára àwọn tó ń ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìwádìí ọlọ́paá rèé lórí àwọn 21 tó kú lẹ́yìn tí oníwàásù ní kí wọ́n fí ebi pa ara wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede Kenya ni awọn ti gbe oku mọkanlelogun jade kuro ni ile ni ilu Malindi lorilẹde naa.
Eyi waye lasiko ti wọn ṣewadii arakunrin oniwaasu kan to sọ fun awọn alatilẹyin rẹ lati fi ebi pa ara wọn ku.
Awọn ọmọde pẹlu awọn oku ti wọn gbe jade naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni o ṣeeṣe ki wọn ri awọn miran ti wọn ti gbẹ mi mi ninu iṣẹlẹ naa.
Iboji oku naa ni wọn gbẹ ni inu igbo akinju Shakakola, ti wọn si doola ẹmi eniyan marundinlogun ti wọn n lọ si ijọ Good News International Church ni ọṣẹ to kọja.
Oniwaasu naa, Paul Mackenzie Nthenge ni o wa ni panpẹ ọlọpaa lọwọ di igba ti yoo fi oju ba ile ẹjọ.
Oniwaasu sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ pe ki wọn fi ebi pa ara wọn ki wọn le pade Jesu
Ileeṣẹ iroyin KBC lorilẹede naa sẹ apejuwe oniwaasu naa gẹgẹ bi adari ẹgbẹ okunkun, ti wọn si ti ri saare mejidinlọgọta bayii.
Lara saree naa ni wọn ti ri oku mọlẹbi marun un to fi mọ ọmọ mẹta pẹlu iya ati baba wọ.
Amọ oniwaasu naa ni oun ko jẹbi ẹsun kankan, ti oun si ti ti ile ijọsin oun lati ọdun 2019.
Amọ ọlọpaa kọ lati gba beeli rẹ.
Iroyin nibe adari ẹgbẹ okunkun naa lo gbe ara rẹ lọ si agọ ọlọpaa lẹyin ti awọn ọmọ meji fi awẹ gba ẹmi ara wọn.
Ọjọ Karundinlogun, Osu Kẹrin ni wọn fi panpẹ ọba gbe lẹyin ti awọn mẹrin miran ku lasiko ti wọn fi ebi pa ara wọn.
Wọ́n ṣekúpa èèyàn 10 tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí kan ṣoṣo lásìkò ètùtù lọ́dọ̀ babaláwo àṣírí tú!

Oríṣun àwòrán, SA POLICE
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afurasi kan lasiko ti etutu n lọ lọwọ lẹyin ti wọn fẹsun kan pe wọn pa eeyan mẹwa latinu mọlẹbi kan ṣoṣo.
Iroyin ni awọn ti ọwọ ofin tẹ yii lọwọ ninu iku eeyan mẹwaa naa lọjọ Ẹti ti iṣẹlẹ aburu naa waye ti iroyin si jade pe awọn kan ṣe ikọlu si mọlẹbi kan ti wọn si ṣekupa eeyan mẹwaa loju ẹsẹ.
Ẹni to kere ju ninu mọlẹbi ọhun jẹ ọmọkunrin ọmọ ọdun mẹtala gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ.
“Gẹgẹ bi iroyin ti ọlọpaa kọkọ sọ, awọn agbebọn dede yabo ilekan ni Pietermaritzburg ti wọn si kọlu mọlẹbi kan”, ileeṣẹ ọlọpaa sọ bẹẹ.
Ni oṣu bii melo kan sẹyin, orilẹede South Africa ti ni ọpọlọpọ akọsilẹ iṣẹlẹ ibọn yinyin.
Awọn iroyin abẹle jabọ pe lara awọn iṣẹlẹ naa ni ṣe pẹlu awọn awakọ taxi nigba ti awọn mii lero pe o ni ṣe pẹlu ija laarin awọn to n gbe oogun oloro.
Bawo ni etutu ṣe ja si iku fun idile kanṣoṣo?

Oríṣun àwòrán, SA Police
Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni aarọ kutukutu ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹrin ni ilu Pietermaritzburg ni ẹkun KwaZulu-Natal, orilẹede South Africa.
Awọn ọlọpaa sọ pe nigba ti awọn de ibi ti iṣẹlẹ ibọn naa ti ṣẹlẹ, wọn kede lẹsẹkẹsẹ pe awọn eeyan naa ti ku.
Wọn ni awọn gbiyanju lati gbe eeyan eeyan mọkanla atawọn mii to fara gba ọta lọ si ileewosan – meji lara awọn yii pada ku ni.
Awọn araalu ti n bẹ ijọba pe ki wọn fi kun akitiyan awọn ọlọpaa ni Kwazulu Natal.
Ki ni ọlọpaa ṣe?

Oríṣun àwòrán, SA Police
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede South Africa ti wọn n pe ni Saps sọ ninu atẹjade kan pe wọn ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ bo ṣe n gbona fẹlifẹli.
Bakan naa lo ni wọn ti bẹrẹ si ni wa awọn agbebọn ọhun ki wọn to lọ jina.
“Awọn ọlọpaa gb igbesẹ pẹli ṣiṣe iṣẹ aṣekara ati amulo ọgbọn ori pẹlu ohun ti wọn gbọ latọdọ awọn araalu lati bẹrẹ si ni wa awọn afurasi to yinbọn nibi iṣẹlẹ aburu naa.
Themba ṣalaye pe “iro ibọn bẹrẹ si ni dun ni bii kilomita meji sibi ti awọn ọlọpaa si doju ija kọ ọkunrin mẹrin to n kopa ninu “etutu” pẹlu oniṣegun ibilẹ kan.
“Ọlọpaa ti mu meji lara awọn afurasi mẹrin naa, ọkan wa labẹ abojuto ọlọpaa nileewosan lẹyin to farapa nigba ti ọlọpaa doju kọ wọn pẹlu ibọn”.
Wọn ni ọkan lara awọn afurasi naa ti na papa bora nigba ti ọkan gbẹmi mi. “Ibọn mẹta ni ọlọpaa gba nibẹ”.
Ọlọpaa ni awọn si n ṣiṣẹ lati wa awọn afurasi mii to lee lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.













