Irọ̀ ní, a kò tíì kéde Aláàfin tuntun - Ìjọba Ìpínlẹ̀ Oyo

Makinde

Oríṣun àwòrán, Others

Ìjọba ipinlẹ Oyo, Lọjọru ti wọgile iroyin kan to gba ori ayelujara pe ìjọba tí kede Alaafin tuntun lẹyin ọdun kan tí Ọba Lamidi Adeyemi III waja.

Kọmisọnna fun iroyin ati asa, Wasiu Olatunbosun lo salaye ọrọ naa.

O ni iroyin ofege ni pe ìjọba ìpinlẹ tí kede Lukman Gbadegesin gẹgẹ Alaafin tuntun ati pe ìjọba ko ti buwọlu ẹnikẹni fun ipo Ọba naa.

Olatunbosun ni gbogbo erongba ìjọba ìpinlẹ Oyo ni lati ri pe wọn tẹle ohun to tọ lori yiyan Ọba tuntun ati pe to ba to asiko, ìjọba yoo fi to araalu leti

"A gbọdọ tẹle ohun to tọ, ìjọba ko ti yan ẹnikẹni di asiko yii. Gomina Seyi Makinde ti sọ fun pe ki wọn pada lọ ṣe ohun to tọ. Ti wọn ba tí ṣe, ijọba yoo se ikede fun araalu."

Saaju ni awọn ileeṣẹ iroyin kan n gbe kiri pe ìjọba ìpinlẹ Oyo tí setan lati kede Lukman Gbadegesin gẹgẹ bii Alaafin tuntun.

Ọdun to kọja ni Alaafin tẹlẹ, Lamidi Adeyemi III waja.

Ìgbésẹ̀ láti yan Aláàfin tuntun ń lọ lọ́wọ́- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ọrọ lede wi pe igbese lati yan Alaafin tuntun ti n lọ lọwọ.

Ọrọ yii jade lẹyin ọdun kan ti Alaafin ana, Ọba Lamidi Adeyemi III re iwalẹ aṣa.

Kọmisọnna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ n'ipinlẹ Ọyọ, Olasunkanmi Olaleye lọ sọ ọrọ yii di mimọ ninu ifọrọwerọ kan ti o ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Ibadan.

Olaleye fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo eeyan ilu ni ijọba yoo sọ fun lẹyin ti wọn ba fi ẹnu ko lori ẹni ti yoo gun ori aleefa Alaafin Ọyọ.

Saaju ni ọkan lara awọn afọbaje ilu Ọyọ, Laguna Ọyọ ti o tun jẹ Oloye agba, Oloye Akindele Oyedepo sọ fun awọn akọroyin pe lati inu oṣu kẹwaa, ọdun 2022 ni awọn afọbaje ilu naa ti jabọ fun ijọba lori ẹni ti oye Alaafin kan.

O ni ibasepọ to wa laarin Gomina Ṣeyi Makinde ati Alaafin ana le ṣokunfa bi nnkan ṣe n falẹ lori igbese lati yan Alaafin tuntun, nitori pe o ṣeeṣe ki Makinde maa ṣe ọfọ Ọba Adeyemi titi di asiko yii.

Lati igba ti Ọba Adeyemi ti waja ni aibalẹ ọkan ati awuyewuye ti rọ mọ igbesẹ lati yan Alaafin tuntun.

Iwadii fi idi rẹ mulẹ wi pe aisi Alaafin l'Ọyọ lo mu ki ilu naa wa lai ni Imaamu agba, nitori Alaafin nikan lo le yan Imaamu agba sipo.

Lẹyin oṣu diẹ ti Ọba Adeyemi waja naa ni Imaamu agba tẹleri nilu Ọyọ, Sheikh Mashood Abdul Ganiyy Adebayo Ajokidero III naa re ibi agba n re.

Igbagbọ wa wi pe o di igba ti Alaafin tuntun ba jẹ ki ilu Ọyọ ti ni Imaamu tuntun.