Dúkìá ṣòfò bí báràkì ọlọ́pàá ṣe dàwó ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, NEMA
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní orílẹ̀ èdè, NEMA ti ní kò sí ẹ̀mí kankan tó sọnù síbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilé tó dàwó ní ọgbà ilé ìgbé àwọn ọlọ́pàá tó wà ní agbègbè Sango, ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.
Adarí ẹkùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù NEMA, Saheed Akiode Akande sọ fún àwọn akọ̀ròyìn ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú pé bí ẹnikẹ́ni kò ṣe bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ní kò sí ẹni tó farapa níbẹ̀.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ilé alájà méjì nínú ọgbà báràkì àwọn ọlọ́pàá tó wà ní agbègbè Sango ní ìlú Ibadan ṣàdédé dàwó lulẹ̀.
Akiode ní ilé náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tó ti pẹ́ tó wà nínú báràkì náà tó sì ti ń sọ̀kò láti ọjọ́ pípẹ́.
Ó ní láti ìgbà náà ni àwọn tó ń gbé nínú rẹ̀ ti kó kúrò lójúnà àti lè dènà ìjàmbá tó le ti irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí yọ.
Ọ̀gá NEMA náà ní àwọn kan ń lo ilé tó dàwọ náà gẹ́gẹ́ bí yàrá ìdáná àmọ́ kò sí ẹni tó ń gbé nínú ilé náà gangan mọ́.
Ó fi kun pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́ta àti ọ̀kadà méjì tí ilé náà dàwọ lé lórí ni àwọn ti rí yọ báyìí àmọ́ àwọn ọkọ̀ náà ti bàjẹ́ kọjá ohun tí wọ́n le tún ṣe.
Bákan náà ló ní àwọn ẹ̀ro amúnáwá jẹnẹrétọ̀ mẹ́rin ṣì wà tó há sábẹ́ ilé náà tí ìgbìyànjú ṣì ń lọ láti yọ wọ́n.
Akiode tún ṣàlàyé pé gbogbo àwọn 168 tó ń gbé nínú báràkì náà ni àwọn ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọn kò sun inú ọgbà náà nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Ó ní àwọn ilé tó wà nínú bárákì náà ló ti di ẹgẹrẹ mìtì àti pé àwọn yóò ṣe àyẹ̀wò àwọn ilé yòókù láti mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn lè padà sí ilé wọn.















